Quran Apps in many lanuages:

Surah Hud Ayahs #116 Translated in Yoruba

فَاسْتَقِمْ كَمَا أُمِرْتَ وَمَنْ تَابَ مَعَكَ وَلَا تَطْغَوْا ۚ إِنَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
Duro sinsin gege bi A se pa iwo ati enikeni ti o ba ronu piwada pelu re lase. E ma se tayo enu-ala. Dajudaju Oun ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise
وَلَا تَرْكَنُوا إِلَى الَّذِينَ ظَلَمُوا فَتَمَسَّكُمُ النَّارُ وَمَا لَكُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ مِنْ أَوْلِيَاءَ ثُمَّ لَا تُنْصَرُونَ
E ma se te sodo awon t’o sabosi nitori ki Ina ma baa fowo ba yin. Ko si nii si awon alaabo fun yin leyin Allahu. Leyin naa, A o nii ran yin lowo
وَأَقِمِ الصَّلَاةَ طَرَفَيِ النَّهَارِ وَزُلَفًا مِنَ اللَّيْلِ ۚ إِنَّ الْحَسَنَاتِ يُذْهِبْنَ السَّيِّئَاتِ ۚ ذَٰلِكَ ذِكْرَىٰ لِلذَّاكِرِينَ
Kirun ni ibere ati ipari osan (iyen, irun Subh, Thuhr ati ‘Asr) ati ni ibere oru (iyen, irun Mogrib ati ‘Isa’). Dajudaju awon ise rere n pa awon ise aburu re. Iyen ni iranti fun awon oluranti (Allahu)
وَاصْبِرْ فَإِنَّ اللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجْرَ الْمُحْسِنِينَ
Se suuru. Dajudaju Allahu ko nii fi esan awon oluse-rere rare
فَلَوْلَا كَانَ مِنَ الْقُرُونِ مِنْ قَبْلِكُمْ أُولُو بَقِيَّةٍ يَنْهَوْنَ عَنِ الْفَسَادِ فِي الْأَرْضِ إِلَّا قَلِيلًا مِمَّنْ أَنْجَيْنَا مِنْهُمْ ۗ وَاتَّبَعَ الَّذِينَ ظَلَمُوا مَا أُتْرِفُوا فِيهِ وَكَانُوا مُجْرِمِينَ
Ki o si je pe awon onilaakaye kan wa ninu awon iran t’o siwaju yin (ninu awon ti A pare) ki won maa ko ibaje lori ile – afi eniyan die lara awon ti A gbala ninu won. - Awon t’o sabosi si tele nnkan ti A fi se gbedemuke fun won. Won si je elese

Choose other languages: