Quran Apps in many lanuages:

Surah Fatir Ayahs #42 Translated in Yoruba

إِنَّ اللَّهَ عَالِمُ غَيْبِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
Dajudaju Allahu ni Onimo-ikoko awon sanmo ati ile. Dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda
هُوَ الَّذِي جَعَلَكُمْ خَلَائِفَ فِي الْأَرْضِ ۚ فَمَنْ كَفَرَ فَعَلَيْهِ كُفْرُهُ ۖ وَلَا يَزِيدُ الْكَافِرِينَ كُفْرُهُمْ عِنْدَ رَبِّهِمْ إِلَّا مَقْتًا ۖ وَلَا يَزِيدُ الْكَافِرِينَ كُفْرُهُمْ إِلَّا خَسَارًا
Oun ni Eni t’O n fi yin se arole lori ile. Nitori naa, eni ti o ba sai gbagbo, (iya) aigbagbo re wa lori re. Aigbagbo awon alaigbagbo ko si nii fun won ni alekun kan lodo Oluwa won bi ko se ibinu. Aigbagbo awon alaigbagbo ko si nii fun won ni alekun kan bi ko se ofo
قُلْ أَرَأَيْتُمْ شُرَكَاءَكُمُ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ أَرُونِي مَاذَا خَلَقُوا مِنَ الْأَرْضِ أَمْ لَهُمْ شِرْكٌ فِي السَّمَاوَاتِ أَمْ آتَيْنَاهُمْ كِتَابًا فَهُمْ عَلَىٰ بَيِّنَتٍ مِنْهُ ۚ بَلْ إِنْ يَعِدُ الظَّالِمُونَ بَعْضُهُمْ بَعْضًا إِلَّا غُرُورًا
So pe: “E so fun mi nipa awon orisa yin ti e n pe leyin Allahu, e fi ohun ti won da han mi lori ile? Tabi won ni ipin kan (pelu Allahu) nibi (iseda) awon sanmo? Tabi A fun won ni tira kan, ti won ni eri t’o yanju ninu re? Rara o! Ko si adehun kan ti awon alabosi, apa kan won n se fun apa kan bi ko se etan.”
إِنَّ اللَّهَ يُمْسِكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ أَنْ تَزُولَا ۚ وَلَئِنْ زَالَتَا إِنْ أَمْسَكَهُمَا مِنْ أَحَدٍ مِنْ بَعْدِهِ ۚ إِنَّهُ كَانَ حَلِيمًا غَفُورًا
Dajudaju Allahu l’O n mu awon sanmo ati ile duro sinsin ti won ko fi ye lule. Dajudaju ti won ba si ye lule, ko si eni kan kan ti o maa mu un duro leyin Re. Dajudaju Allahu n je Alafarada, Alaforijin
وَأَقْسَمُوا بِاللَّهِ جَهْدَ أَيْمَانِهِمْ لَئِنْ جَاءَهُمْ نَذِيرٌ لَيَكُونُنَّ أَهْدَىٰ مِنْ إِحْدَى الْأُمَمِ ۖ فَلَمَّا جَاءَهُمْ نَذِيرٌ مَا زَادَهُمْ إِلَّا نُفُورًا
Won si fi Allahu bura ti ibura won si lagbara gan-an pe: "Dajudaju ti olukilo kan ba fi le wa ba awon, dajudaju awon yoo mona taara ju eyikeyii ninu ijo (t’o ti siwaju) lo." Nigba ti olukilo si wa ba won, (eyi) ko se alekun kan fun won bi ko se sisa (fun ododo)

Choose other languages: