Quran Apps in many lanuages:

Surah Az-Zukhruf Ayahs #37 Translated in Yoruba

وَلَوْلَا أَنْ يَكُونَ النَّاسُ أُمَّةً وَاحِدَةً لَجَعَلْنَا لِمَنْ يَكْفُرُ بِالرَّحْمَٰنِ لِبُيُوتِهِمْ سُقُفًا مِنْ فِضَّةٍ وَمَعَارِجَ عَلَيْهَا يَظْهَرُونَ
Ati pe ti ki i ba se pe awon eniyan maa je ijo kan soso (lori aigbagbo ni), A iba se awon orule ati awon akaba ti won yoo fi maa gunke ninu ile ni fadaka fun eni t’o n sai gbagbo ninu Ajoke-aye
وَلِبُيُوتِهِمْ أَبْوَابًا وَسُرُرًا عَلَيْهَا يَتَّكِئُونَ
(A iba tun se) awon enu ona ile won ati awon ibusun ti won yoo maa rogboku le lori (ni fadaka)
وَزُخْرُفًا ۚ وَإِنْ كُلُّ ذَٰلِكَ لَمَّا مَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۚ وَالْآخِرَةُ عِنْدَ رَبِّكَ لِلْمُتَّقِينَ
ati goolu. Gbogbo nnkan wonyi ko je nnkan kan bi ko se igbadun isemi aye lasan. (Ogba Idera) Orun si wa ni odo Oluwa re fun awon oluberu (Allahu)
وَمَنْ يَعْشُ عَنْ ذِكْرِ الرَّحْمَٰنِ نُقَيِّضْ لَهُ شَيْطَانًا فَهُوَ لَهُ قَرِينٌ
Enikeni ti o ba gbunri kuro nibi iranti Ajoke-aye, A maa yan esu kan fun un. Oun si ni alabaarin re
وَإِنَّهُمْ لَيَصُدُّونَهُمْ عَنِ السَّبِيلِ وَيَحْسَبُونَ أَنَّهُمْ مُهْتَدُونَ
Dajudaju awon esu naa yoo maa seri won kuro loju ona (esin Allahu). Won yo si maa lero pe dajudaju awon ni olumona

Choose other languages: