Quran Apps in many lanuages:

Surah Az-Zukhruf Ayahs #39 Translated in Yoruba

وَزُخْرُفًا ۚ وَإِنْ كُلُّ ذَٰلِكَ لَمَّا مَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۚ وَالْآخِرَةُ عِنْدَ رَبِّكَ لِلْمُتَّقِينَ
ati goolu. Gbogbo nnkan wonyi ko je nnkan kan bi ko se igbadun isemi aye lasan. (Ogba Idera) Orun si wa ni odo Oluwa re fun awon oluberu (Allahu)
وَمَنْ يَعْشُ عَنْ ذِكْرِ الرَّحْمَٰنِ نُقَيِّضْ لَهُ شَيْطَانًا فَهُوَ لَهُ قَرِينٌ
Enikeni ti o ba gbunri kuro nibi iranti Ajoke-aye, A maa yan esu kan fun un. Oun si ni alabaarin re
وَإِنَّهُمْ لَيَصُدُّونَهُمْ عَنِ السَّبِيلِ وَيَحْسَبُونَ أَنَّهُمْ مُهْتَدُونَ
Dajudaju awon esu naa yoo maa seri won kuro loju ona (esin Allahu). Won yo si maa lero pe dajudaju awon ni olumona
حَتَّىٰ إِذَا جَاءَنَا قَالَ يَا لَيْتَ بَيْنِي وَبَيْنَكَ بُعْدَ الْمَشْرِقَيْنِ فَبِئْسَ الْقَرِينُ
Titi di igba ti o fi maa wa ba Wa, o si maa wi pe: "Haa! Ki o si je pe (itakete bi) itakete ibuyo-oorun ati ibuwo re si wa laaarin emi ati iwo (esu alabaarin yii, iba dara); alabaarin buruku si ni
وَلَنْ يَنْفَعَكُمُ الْيَوْمَ إِذْ ظَلَمْتُمْ أَنَّكُمْ فِي الْعَذَابِ مُشْتَرِكُونَ
(Abamo yin) ko nii se yin ni anfaani ni Oni nigba ti e ti sabosi. (Ati pe) dajudaju eyin (ati orisa yin) ni akegbe ninu iya

Choose other languages: