Surah Az-Zamar Ayahs #71 Translated in Yoruba
وَمَا قَدَرُوا اللَّهَ حَقَّ قَدْرِهِ وَالْأَرْضُ جَمِيعًا قَبْضَتُهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَالسَّمَاوَاتُ مَطْوِيَّاتٌ بِيَمِينِهِ ۚ سُبْحَانَهُ وَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ
Won ko bu iyi fun Allahu bi o se to lati bu iyi fun Un. Gbogbo ile patapata si ni (Allahu) maa fowo ara Re gbamu ni Ojo Ajinde. O si maa fi owo otun Re ka sanmo korobojo. Mimo ni fun Un. O si ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I
وَنُفِخَ فِي الصُّورِ فَصَعِقَ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَمَنْ فِي الْأَرْضِ إِلَّا مَنْ شَاءَ اللَّهُ ۖ ثُمَّ نُفِخَ فِيهِ أُخْرَىٰ فَإِذَا هُمْ قِيَامٌ يَنْظُرُونَ
Won a fon fere oniwo fun iku. Awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile si maa ku afi eni ti Allahu ba fe. Leyin naa, won maa fon on ni ee keji, nigba naa won maa wa ni idide. Won yo si maa wo sun
وَأَشْرَقَتِ الْأَرْضُ بِنُورِ رَبِّهَا وَوُضِعَ الْكِتَابُ وَجِيءَ بِالنَّبِيِّينَ وَالشُّهَدَاءِ وَقُضِيَ بَيْنَهُمْ بِالْحَقِّ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ
Ati pe ile naa yoo maa tan yanranyanran pelu imole Oluwa re. Won maa gbe iwe ise eda lele. Won si maa mu awon Anabi ati awon elerii wa. A o si sedajo laaarin won pelu ododo. A o si nii sabosi si won
وَوُفِّيَتْ كُلُّ نَفْسٍ مَا عَمِلَتْ وَهُوَ أَعْلَمُ بِمَا يَفْعَلُونَ
Ati pe Won maa san emi kookan ni esan ohun ti o se nise. Allahu si nimo julo nipa ohun ti won n se nise
وَسِيقَ الَّذِينَ كَفَرُوا إِلَىٰ جَهَنَّمَ زُمَرًا ۖ حَتَّىٰ إِذَا جَاءُوهَا فُتِحَتْ أَبْوَابُهَا وَقَالَ لَهُمْ خَزَنَتُهَا أَلَمْ يَأْتِكُمْ رُسُلٌ مِنْكُمْ يَتْلُونَ عَلَيْكُمْ آيَاتِ رَبِّكُمْ وَيُنْذِرُونَكُمْ لِقَاءَ يَوْمِكُمْ هَٰذَا ۚ قَالُوا بَلَىٰ وَلَٰكِنْ حَقَّتْ كَلِمَةُ الْعَذَابِ عَلَى الْكَافِرِينَ
Won yo si da awon t’o sai gbagbo lo sinu ina Jahnamo nijonijo, titi di igba ti won ba de ibe, won maa si awon ilekun re sile (fun won). Awon eso re yo si so fun won pe: "Nje awon Ojise kan ko wa ba yin lati aarin ara yin, ti won n ke awon ayah Oluwa yin fun yin, ti won si n kilo ipade ojo yin oni yii fun yin?" Won wi pe: "Rara (won wa ba wa)." Sugbon oro iya ko le awon alaigbagbo lori ni
Choose other languages:

Albanian

Amharic

Azerbaijani

Bengali

Bosnian

Bulgarian

Burmese

Chinese

Danish

Dutch

English

Farsi

Filipino

French

Fulah

German

Gujarati

Hausa

Hindi

Indonesian

Italian

Japanese

Jawa

Kazakh

Khmer

Korean

Kurdish

Kyrgyz

Malay

Malayalam

Norwegian

Pashto

Persian

Polish

Portuguese

Punjabi

Russian

Sindhi

Sinhalese

Somali

Spanish

Swahili

Swedish

Tajik

Tamil

Tatar

Telugu

Thai

Turkish

Urdu

Uyghur

Uzbek

Vietnamese

Yoruba
