Quran Apps in many lanuages:

Surah Az-Zamar Ayahs #73 Translated in Yoruba

وَأَشْرَقَتِ الْأَرْضُ بِنُورِ رَبِّهَا وَوُضِعَ الْكِتَابُ وَجِيءَ بِالنَّبِيِّينَ وَالشُّهَدَاءِ وَقُضِيَ بَيْنَهُمْ بِالْحَقِّ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ
Ati pe ile naa yoo maa tan yanranyanran pelu imole Oluwa re. Won maa gbe iwe ise eda lele. Won si maa mu awon Anabi ati awon elerii wa. A o si sedajo laaarin won pelu ododo. A o si nii sabosi si won
وَوُفِّيَتْ كُلُّ نَفْسٍ مَا عَمِلَتْ وَهُوَ أَعْلَمُ بِمَا يَفْعَلُونَ
Ati pe Won maa san emi kookan ni esan ohun ti o se nise. Allahu si nimo julo nipa ohun ti won n se nise
وَسِيقَ الَّذِينَ كَفَرُوا إِلَىٰ جَهَنَّمَ زُمَرًا ۖ حَتَّىٰ إِذَا جَاءُوهَا فُتِحَتْ أَبْوَابُهَا وَقَالَ لَهُمْ خَزَنَتُهَا أَلَمْ يَأْتِكُمْ رُسُلٌ مِنْكُمْ يَتْلُونَ عَلَيْكُمْ آيَاتِ رَبِّكُمْ وَيُنْذِرُونَكُمْ لِقَاءَ يَوْمِكُمْ هَٰذَا ۚ قَالُوا بَلَىٰ وَلَٰكِنْ حَقَّتْ كَلِمَةُ الْعَذَابِ عَلَى الْكَافِرِينَ
Won yo si da awon t’o sai gbagbo lo sinu ina Jahnamo nijonijo, titi di igba ti won ba de ibe, won maa si awon ilekun re sile (fun won). Awon eso re yo si so fun won pe: "Nje awon Ojise kan ko wa ba yin lati aarin ara yin, ti won n ke awon ayah Oluwa yin fun yin, ti won si n kilo ipade ojo yin oni yii fun yin?" Won wi pe: "Rara (won wa ba wa)." Sugbon oro iya ko le awon alaigbagbo lori ni
قِيلَ ادْخُلُوا أَبْوَابَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا ۖ فَبِئْسَ مَثْوَى الْمُتَكَبِّرِينَ
A oo so pe: "E wo enu ona ina Jahnamo. Olusegbere (ni yin) ninu re. Ibugbe awon olusegberaga si buru
وَسِيقَ الَّذِينَ اتَّقَوْا رَبَّهُمْ إِلَى الْجَنَّةِ زُمَرًا ۖ حَتَّىٰ إِذَا جَاءُوهَا وَفُتِحَتْ أَبْوَابُهَا وَقَالَ لَهُمْ خَزَنَتُهَا سَلَامٌ عَلَيْكُمْ طِبْتُمْ فَادْخُلُوهَا خَالِدِينَ
Ati pe A oo ko awon t’o beru Oluwa won lo sinu Ogba Idera nijonijo, titi di igba ti won ba de ibe, won maa si awon ilekun re sile (fun won). Awon eso re yo si so fun won pe: "Ki alaafia maa ba yin. Eyin se ise t’o dara. Nitori naa, e wo inu Ogba Idera, (ki e di) olusegbere (ninu re)

Choose other languages: