Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #96 Translated in Yoruba

وَلَا عَلَى الَّذِينَ إِذَا مَا أَتَوْكَ لِتَحْمِلَهُمْ قُلْتَ لَا أَجِدُ مَا أَحْمِلُكُمْ عَلَيْهِ تَوَلَّوْا وَأَعْيُنُهُمْ تَفِيضُ مِنَ الدَّمْعِ حَزَنًا أَلَّا يَجِدُوا مَا يُنْفِقُونَ
Ko tun si ese fun awon ti (o je pe) nigba ti won ba wa ba o pe ki o fun awon ni nnkan ti awon yoo gun (lo soju ogun), ti o si so pe, “Ng o ri nnkan ti mo le fun yin gun (lo soju ogun), won maa pada pelu oju won ti yoo maa damije ni ti ibanuje pe won ko ri nnkan ti won maa na (lo soju ogun esin)
إِنَّمَا السَّبِيلُ عَلَى الَّذِينَ يَسْتَأْذِنُونَكَ وَهُمْ أَغْنِيَاءُ ۚ رَضُوا بِأَنْ يَكُونُوا مَعَ الْخَوَالِفِ وَطَبَعَ اللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Awon ti ibawi wa fun ni awon t’o n toro iyonda lodo re (lati jokoo sile, ti) won si je oloro, ti won yonu si ki won wa pelu awon olusaseyin fun ogun esin. Allahu ti fi edidi di okan won pa; nitori naa, won ko si mo
يَعْتَذِرُونَ إِلَيْكُمْ إِذَا رَجَعْتُمْ إِلَيْهِمْ ۚ قُلْ لَا تَعْتَذِرُوا لَنْ نُؤْمِنَ لَكُمْ قَدْ نَبَّأَنَا اللَّهُ مِنْ أَخْبَارِكُمْ ۚ وَسَيَرَى اللَّهُ عَمَلَكُمْ وَرَسُولُهُ ثُمَّ تُرَدُّونَ إِلَىٰ عَالِمِ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ فَيُنَبِّئُكُمْ بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ
Won yoo mu awawi wa fun yin nigba ti e ba dari de ba won. So pe: "E ma se mu awawi wa; a o nii gba yin gbo. Allahu kuku ti so awon oro yin fun wa. Allahu ati Ojise Re yo si ri ise (owo) yin. Leyin naa, A oo da yin pada si odo Onimo-ikoko ati gbangba. Nigba naa, O maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise
سَيَحْلِفُونَ بِاللَّهِ لَكُمْ إِذَا انْقَلَبْتُمْ إِلَيْهِمْ لِتُعْرِضُوا عَنْهُمْ ۖ فَأَعْرِضُوا عَنْهُمْ ۖ إِنَّهُمْ رِجْسٌ ۖ وَمَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ
Won yoo maa fi Allahu bura fun yin nigba ti e ba dari de ba won, nitori ki e le pa won ti. Nitori naa, e pa won ti; dajudaju egbin ni won. Ina Jahanamo si ni ibugbe won. (O je) esan nitori ohun ti won n se nise
يَحْلِفُونَ لَكُمْ لِتَرْضَوْا عَنْهُمْ ۖ فَإِنْ تَرْضَوْا عَنْهُمْ فَإِنَّ اللَّهَ لَا يَرْضَىٰ عَنِ الْقَوْمِ الْفَاسِقِينَ
Won yoo maa bura fun yin nitori ki e le yonu si won. Ti e ba yonu si won, dajudaju Allahu ko nii yonu si ijo obileje

Choose other languages: