Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #35 Translated in Yoruba

اتَّخَذُوا أَحْبَارَهُمْ وَرُهْبَانَهُمْ أَرْبَابًا مِنْ دُونِ اللَّهِ وَالْمَسِيحَ ابْنَ مَرْيَمَ وَمَا أُمِرُوا إِلَّا لِيَعْبُدُوا إِلَٰهًا وَاحِدًا ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۚ سُبْحَانَهُ عَمَّا يُشْرِكُونَ
Won mu awon alufaa won (ninu yehudi) ati awon alufaa won (ninu nasara) ni oluwa leyin Allahu. (Won tun mu) Mosih omo Moryam (ni oluwa leyin Allahu). Bee si ni A o pa won lase kan tayo jijosin fun Olohun, Okan soso. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. O mo tayo nnkan ti won n fi sebo si I
يُرِيدُونَ أَنْ يُطْفِئُوا نُورَ اللَّهِ بِأَفْوَاهِهِمْ وَيَأْبَى اللَّهُ إِلَّا أَنْ يُتِمَّ نُورَهُ وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ
Won fe fi enu won pa imole (esin) Allahu, Allahu yo si ko (fun won) titi O fi maa pe imole (esin) Re, awon alaigbagbo ibaa korira re
هُوَ الَّذِي أَرْسَلَ رَسُولَهُ بِالْهُدَىٰ وَدِينِ الْحَقِّ لِيُظْهِرَهُ عَلَى الدِّينِ كُلِّهِ وَلَوْ كَرِهَ الْمُشْرِكُونَ
(Allahu) Oun ni Eni ti O fi imona ati esin ododo (esin ’Islam) ran Ojise Re nitori ki O le fi bori esin (miiran), gbogbo re patapata, awon osebo ibaa korira re
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّ كَثِيرًا مِنَ الْأَحْبَارِ وَالرُّهْبَانِ لَيَأْكُلُونَ أَمْوَالَ النَّاسِ بِالْبَاطِلِ وَيَصُدُّونَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ ۗ وَالَّذِينَ يَكْنِزُونَ الذَّهَبَ وَالْفِضَّةَ وَلَا يُنْفِقُونَهَا فِي سَبِيلِ اللَّهِ فَبَشِّرْهُمْ بِعَذَابٍ أَلِيمٍ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, opolopo ninu awon alufaa (ninu yehudi) ati awon alufaa (ninu nasara), won kuku n fi ona eru je dukia awon eniyan ni, won si n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Awon t’o si n ko wura ati fadaka jo, won ko si na an fun esin Allahu, fun won ni iro iya eleta-elero
يَوْمَ يُحْمَىٰ عَلَيْهَا فِي نَارِ جَهَنَّمَ فَتُكْوَىٰ بِهَا جِبَاهُهُمْ وَجُنُوبُهُمْ وَظُهُورُهُمْ ۖ هَٰذَا مَا كَنَزْتُمْ لِأَنْفُسِكُمْ فَذُوقُوا مَا كُنْتُمْ تَكْنِزُونَ
Ni ojo ti A oo maa yo (wura ati fadaka naa) ninu ina Jahanamo, A o si maa fi jo iwaju won, egbe won ati eyin won. (A si maa so pe): "Eyi ni ohun ti e ko jo fun emi ara yin. Nitori naa, e to ohun ti e ko jo wo

Choose other languages: