Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #37 Translated in Yoruba

هُوَ الَّذِي أَرْسَلَ رَسُولَهُ بِالْهُدَىٰ وَدِينِ الْحَقِّ لِيُظْهِرَهُ عَلَى الدِّينِ كُلِّهِ وَلَوْ كَرِهَ الْمُشْرِكُونَ
(Allahu) Oun ni Eni ti O fi imona ati esin ododo (esin ’Islam) ran Ojise Re nitori ki O le fi bori esin (miiran), gbogbo re patapata, awon osebo ibaa korira re
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّ كَثِيرًا مِنَ الْأَحْبَارِ وَالرُّهْبَانِ لَيَأْكُلُونَ أَمْوَالَ النَّاسِ بِالْبَاطِلِ وَيَصُدُّونَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ ۗ وَالَّذِينَ يَكْنِزُونَ الذَّهَبَ وَالْفِضَّةَ وَلَا يُنْفِقُونَهَا فِي سَبِيلِ اللَّهِ فَبَشِّرْهُمْ بِعَذَابٍ أَلِيمٍ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, opolopo ninu awon alufaa (ninu yehudi) ati awon alufaa (ninu nasara), won kuku n fi ona eru je dukia awon eniyan ni, won si n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Awon t’o si n ko wura ati fadaka jo, won ko si na an fun esin Allahu, fun won ni iro iya eleta-elero
يَوْمَ يُحْمَىٰ عَلَيْهَا فِي نَارِ جَهَنَّمَ فَتُكْوَىٰ بِهَا جِبَاهُهُمْ وَجُنُوبُهُمْ وَظُهُورُهُمْ ۖ هَٰذَا مَا كَنَزْتُمْ لِأَنْفُسِكُمْ فَذُوقُوا مَا كُنْتُمْ تَكْنِزُونَ
Ni ojo ti A oo maa yo (wura ati fadaka naa) ninu ina Jahanamo, A o si maa fi jo iwaju won, egbe won ati eyin won. (A si maa so pe): "Eyi ni ohun ti e ko jo fun emi ara yin. Nitori naa, e to ohun ti e ko jo wo
إِنَّ عِدَّةَ الشُّهُورِ عِنْدَ اللَّهِ اثْنَا عَشَرَ شَهْرًا فِي كِتَابِ اللَّهِ يَوْمَ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ مِنْهَا أَرْبَعَةٌ حُرُمٌ ۚ ذَٰلِكَ الدِّينُ الْقَيِّمُ ۚ فَلَا تَظْلِمُوا فِيهِنَّ أَنْفُسَكُمْ ۚ وَقَاتِلُوا الْمُشْرِكِينَ كَافَّةً كَمَا يُقَاتِلُونَكُمْ كَافَّةً ۚ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ مَعَ الْمُتَّقِينَ
Dajudaju onka awon osu lodo Allahu n je osu mejila ninu akosile ti Allahu ni ojo ti O ti da awon sanmo ati ile. Merin ni osu owo ninu re. Iyen ni esin t’o fese rinle. Nitori naa, e ma sabosi si ara yin ninu awon osu owo. Ki gbogbo yin si gbogun ti awon osebo gege bi gbogbo won se n gbogun ti yin. Ki e si mo pe dajudaju Allahu wa pelu awon oluberu (Re)
إِنَّمَا النَّسِيءُ زِيَادَةٌ فِي الْكُفْرِ ۖ يُضَلُّ بِهِ الَّذِينَ كَفَرُوا يُحِلُّونَهُ عَامًا وَيُحَرِّمُونَهُ عَامًا لِيُوَاطِئُوا عِدَّةَ مَا حَرَّمَ اللَّهُ فَيُحِلُّوا مَا حَرَّمَ اللَّهُ ۚ زُيِّنَ لَهُمْ سُوءُ أَعْمَالِهِمْ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْكَافِرِينَ
Alekun ninu aigbagbo ni didajo si awon osu owo (lati owo awon osebo). Won n fi ko isina ba awon t’o sai gbagbo (nipa pe) won n se osu owo kan ni osu eto (fun ogun jija) ninu odun kan, won si n bu owo fun osu (ti ki i se osu owo) ninu odun (miiran, won ko si nii jagun ninu re) nitori ki won le yo onka osu ti Allahu se ni owo sira won. Won si tipase bee se ni eto ohun ti Allahu se ni eewo. Won se ise aburu won ni oso fun won. Allahu ko nii fi ona mo ijo alaigbagbo

Choose other languages: