Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #23 Translated in Yoruba

أَجَعَلْتُمْ سِقَايَةَ الْحَاجِّ وَعِمَارَةَ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ كَمَنْ آمَنَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَجَاهَدَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ۚ لَا يَسْتَوُونَ عِنْدَ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ
Se e maa se fifun alalaaji ni omi mu ati sise amojuto Mosalasi Haram ni ohun t’o dogba si eni t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, t’o si jagun soju ona (esin) Allahu? Won ko dogba lodo Allahu. Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi
الَّذِينَ آمَنُوا وَهَاجَرُوا وَجَاهَدُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنْفُسِهِمْ أَعْظَمُ دَرَجَةً عِنْدَ اللَّهِ ۚ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْفَائِزُونَ
Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won gbe ilu won ju sile, ti won si fi dukia won ati emi won jagun fun esin Allahu, won tobi julo ni ipo lodo Allahu. Awon wonyen, awon si ni olujere
يُبَشِّرُهُمْ رَبُّهُمْ بِرَحْمَةٍ مِنْهُ وَرِضْوَانٍ وَجَنَّاتٍ لَهُمْ فِيهَا نَعِيمٌ مُقِيمٌ
Oluwa won n fun won ni iro idunnu nipa ike lati odo Re pelu iyonu ati awon Ogba Idera kan ti idera gbere wa fun won ninu re
خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۚ إِنَّ اللَّهَ عِنْدَهُ أَجْرٌ عَظِيمٌ
Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Dajudaju Allahu, odo Re ni esan nla wa
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّخِذُوا آبَاءَكُمْ وَإِخْوَانَكُمْ أَوْلِيَاءَ إِنِ اسْتَحَبُّوا الْكُفْرَ عَلَى الْإِيمَانِ ۚ وَمَنْ يَتَوَلَّهُمْ مِنْكُمْ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon baba yin ati awon arakunrin yin ni ore ayo bi won ba gbola fun aigbagbo lori igbagbo ododo. Enikeni t’o ba mu won ni ore ayo ninu yin, awon wonyen, awon ni alabosi

Choose other languages: