Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #25 Translated in Yoruba

يُبَشِّرُهُمْ رَبُّهُمْ بِرَحْمَةٍ مِنْهُ وَرِضْوَانٍ وَجَنَّاتٍ لَهُمْ فِيهَا نَعِيمٌ مُقِيمٌ
Oluwa won n fun won ni iro idunnu nipa ike lati odo Re pelu iyonu ati awon Ogba Idera kan ti idera gbere wa fun won ninu re
خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۚ إِنَّ اللَّهَ عِنْدَهُ أَجْرٌ عَظِيمٌ
Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Dajudaju Allahu, odo Re ni esan nla wa
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّخِذُوا آبَاءَكُمْ وَإِخْوَانَكُمْ أَوْلِيَاءَ إِنِ اسْتَحَبُّوا الْكُفْرَ عَلَى الْإِيمَانِ ۚ وَمَنْ يَتَوَلَّهُمْ مِنْكُمْ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon baba yin ati awon arakunrin yin ni ore ayo bi won ba gbola fun aigbagbo lori igbagbo ododo. Enikeni t’o ba mu won ni ore ayo ninu yin, awon wonyen, awon ni alabosi
قُلْ إِنْ كَانَ آبَاؤُكُمْ وَأَبْنَاؤُكُمْ وَإِخْوَانُكُمْ وَأَزْوَاجُكُمْ وَعَشِيرَتُكُمْ وَأَمْوَالٌ اقْتَرَفْتُمُوهَا وَتِجَارَةٌ تَخْشَوْنَ كَسَادَهَا وَمَسَاكِنُ تَرْضَوْنَهَا أَحَبَّ إِلَيْكُمْ مِنَ اللَّهِ وَرَسُولِهِ وَجِهَادٍ فِي سَبِيلِهِ فَتَرَبَّصُوا حَتَّىٰ يَأْتِيَ اللَّهُ بِأَمْرِهِ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ
So pe: “Ti o ba je pe awon baba yin, awon omokunrin yin, awon arakunrin yin, awon iyawo yin ati awon ibatan yin pelu awon dukia kan ti e ti ko jo ati okowo kan ti e n beru pe ki o ma kuta ati awon ibugbe ti e yonu si, (ti iwonyi) ba wu yin ju Allahu ati Ojise Re pelu jija ogun soju ona (esin) Re, e maa reti (ikangun) nigba naa titi Allahu yoo fi mu ase Re wa. Allahu ko nii fi ona mo ijo obileje
لَقَدْ نَصَرَكُمُ اللَّهُ فِي مَوَاطِنَ كَثِيرَةٍ ۙ وَيَوْمَ حُنَيْنٍ ۙ إِذْ أَعْجَبَتْكُمْ كَثْرَتُكُمْ فَلَمْ تُغْنِ عَنْكُمْ شَيْئًا وَضَاقَتْ عَلَيْكُمُ الْأَرْضُ بِمَا رَحُبَتْ ثُمَّ وَلَّيْتُمْ مُدْبِرِينَ
Dajudaju Allahu ti se aranse fun yin ni opolopo oju ogun ati ni ojo (ogun) Hunaen, nigba ti pipo yin jo yin loju, (amo) ko ro yin loro kan kan; ile si fun mo yin tohun ti bi o se fe to. Leyin naa, e peyin da, e si n sa seyin

Choose other languages: