Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #113 Translated in Yoruba

أَفَمَنْ أَسَّسَ بُنْيَانَهُ عَلَىٰ تَقْوَىٰ مِنَ اللَّهِ وَرِضْوَانٍ خَيْرٌ أَمْ مَنْ أَسَّسَ بُنْيَانَهُ عَلَىٰ شَفَا جُرُفٍ هَارٍ فَانْهَارَ بِهِ فِي نَارِ جَهَنَّمَ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ
Nje eni ti o fi ipile ile mimo tire lele lori iberu Allahu ati iyonu (Re) l’o loore julo ni tabi eni ti o fi ipile ile mimo tire lele ni egbe kan leti ogbun t’o maa ye lule, ti o si maa ye e lese sinu ina Jahanamo? Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi
لَا يَزَالُ بُنْيَانُهُمُ الَّذِي بَنَوْا رِيبَةً فِي قُلُوبِهِمْ إِلَّا أَنْ تَقَطَّعَ قُلُوبُهُمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Ile won ti won mo kale ko nii ye ko iyemeji sinu okan won titi okan won yoo fi ja kelekele. Allahu si ni Onimo, Ologbon
إِنَّ اللَّهَ اشْتَرَىٰ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ أَنْفُسَهُمْ وَأَمْوَالَهُمْ بِأَنَّ لَهُمُ الْجَنَّةَ ۚ يُقَاتِلُونَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ فَيَقْتُلُونَ وَيُقْتَلُونَ ۖ وَعْدًا عَلَيْهِ حَقًّا فِي التَّوْرَاةِ وَالْإِنْجِيلِ وَالْقُرْآنِ ۚ وَمَنْ أَوْفَىٰ بِعَهْدِهِ مِنَ اللَّهِ ۚ فَاسْتَبْشِرُوا بِبَيْعِكُمُ الَّذِي بَايَعْتُمْ بِهِ ۚ وَذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ
Dajudaju Allahu ra emi awon onigbagbo ododo ati dukia won nitori pe dajudaju tiwon ni Ogba Idera. Won n jagun loju ona (esin) Allahu; won n pa ota esin, won si n pa awon naa. (O je) adehun lodo Allahu. (O je) ododo ninu at-Taorah, al-’Injil ati al-Ƙur’an. Ta si ni o le mu adehun re se ju Allahu? Nitori naa, e dunnu si okowo yin ti e (fi emi ati dukia yin) se. Iyen, ohun si ni erenje nla
التَّائِبُونَ الْعَابِدُونَ الْحَامِدُونَ السَّائِحُونَ الرَّاكِعُونَ السَّاجِدُونَ الْآمِرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَالنَّاهُونَ عَنِ الْمُنْكَرِ وَالْحَافِظُونَ لِحُدُودِ اللَّهِ ۗ وَبَشِّرِ الْمُؤْمِنِينَ
Awon oluronupiwada, awon olujosin (fun Allahu), awon oludupe (fun Allahu), awon alaaawe, awon oludawote-orunkun (lori irun), awon oluforikanle (fun Allahu), awon olupase-ohun rere, awon oluko-ohun buruku ati awon oluso-enu-ala ti Allahu gbekale, fun awon onigbagbo ododo (wonyi) ni iro idunnu (Ogba Idera)
مَا كَانَ لِلنَّبِيِّ وَالَّذِينَ آمَنُوا أَنْ يَسْتَغْفِرُوا لِلْمُشْرِكِينَ وَلَوْ كَانُوا أُولِي قُرْبَىٰ مِنْ بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمْ أَنَّهُمْ أَصْحَابُ الْجَحِيمِ
Ko ye fun Anabi ati awon t’o gbagbo lododo lati toro aforijin fun awon osebo, won ibaa je ebi, leyin ti o ti han si won pe dajudaju ero inu ina Jehim ni won

Choose other languages: