Quran Apps in many lanuages:

Surah Ash-Shura Ayahs #27 Translated in Yoruba

ذَٰلِكَ الَّذِي يُبَشِّرُ اللَّهُ عِبَادَهُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ ۗ قُلْ لَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ أَجْرًا إِلَّا الْمَوَدَّةَ فِي الْقُرْبَىٰ ۗ وَمَنْ يَقْتَرِفْ حَسَنَةً نَزِدْ لَهُ فِيهَا حُسْنًا ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ شَكُورٌ
Iyen ni eyi ti Allahu fi n se iro idunnu fun awon erusin Re, awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere. So pe: "Emi ko beere owo-oya lowo yin lori re bi ko se ife ebi.” Enikeni ti o ba se rere kan, A maa se alekun rere fun un. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Olope
أَمْ يَقُولُونَ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا ۖ فَإِنْ يَشَإِ اللَّهُ يَخْتِمْ عَلَىٰ قَلْبِكَ ۗ وَيَمْحُ اللَّهُ الْبَاطِلَ وَيُحِقُّ الْحَقَّ بِكَلِمَاتِهِ ۚ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
Tabi won n wi pe: "O da adapa iro mo Allahu ni?" Nitori naa, ti Allahu ba fe, O maa fi edidi di okan re pa. Ati pe Allahu yoo pa iro re. O si maa fi ododo rinle pelu oro Re. Dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda
وَهُوَ الَّذِي يَقْبَلُ التَّوْبَةَ عَنْ عِبَادِهِ وَيَعْفُو عَنِ السَّيِّئَاتِ وَيَعْلَمُ مَا تَفْعَلُونَ
Oun ni Eni t’O n gba ironupiwada awon erusin Re. O n se amojukuro nibi awon asise. O si mo ohun ti e n se nise
وَيَسْتَجِيبُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَيَزِيدُهُمْ مِنْ فَضْلِهِ ۚ وَالْكَافِرُونَ لَهُمْ عَذَابٌ شَدِيدٌ
O n gba adua awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere. O si n se alekun fun won ninu ola Re. Awon alaigbagbo, iya lile si wa fun won
وَلَوْ بَسَطَ اللَّهُ الرِّزْقَ لِعِبَادِهِ لَبَغَوْا فِي الْأَرْضِ وَلَٰكِنْ يُنَزِّلُ بِقَدَرٍ مَا يَشَاءُ ۚ إِنَّهُ بِعِبَادِهِ خَبِيرٌ بَصِيرٌ
Ti o ba je pe Allahu te arisiki sile regede fun awon erusin Re ni, won iba tayo enu-ala lori ile. Sugbon O n so (arisiki) ti O ba fe kale niwon-niwon. Dajudaju Oun ni Alamotan, Oluriran nipa awon erusin Re

Choose other languages: