Quran Apps in many lanuages:

Surah Ash-Shura Ayahs #29 Translated in Yoruba

وَهُوَ الَّذِي يَقْبَلُ التَّوْبَةَ عَنْ عِبَادِهِ وَيَعْفُو عَنِ السَّيِّئَاتِ وَيَعْلَمُ مَا تَفْعَلُونَ
Oun ni Eni t’O n gba ironupiwada awon erusin Re. O n se amojukuro nibi awon asise. O si mo ohun ti e n se nise
وَيَسْتَجِيبُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَيَزِيدُهُمْ مِنْ فَضْلِهِ ۚ وَالْكَافِرُونَ لَهُمْ عَذَابٌ شَدِيدٌ
O n gba adua awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere. O si n se alekun fun won ninu ola Re. Awon alaigbagbo, iya lile si wa fun won
وَلَوْ بَسَطَ اللَّهُ الرِّزْقَ لِعِبَادِهِ لَبَغَوْا فِي الْأَرْضِ وَلَٰكِنْ يُنَزِّلُ بِقَدَرٍ مَا يَشَاءُ ۚ إِنَّهُ بِعِبَادِهِ خَبِيرٌ بَصِيرٌ
Ti o ba je pe Allahu te arisiki sile regede fun awon erusin Re ni, won iba tayo enu-ala lori ile. Sugbon O n so (arisiki) ti O ba fe kale niwon-niwon. Dajudaju Oun ni Alamotan, Oluriran nipa awon erusin Re
وَهُوَ الَّذِي يُنَزِّلُ الْغَيْثَ مِنْ بَعْدِ مَا قَنَطُوا وَيَنْشُرُ رَحْمَتَهُ ۚ وَهُوَ الْوَلِيُّ الْحَمِيدُ
Oun si ni Eni t’O n so omi ojo kale leyin igba ti won ti soreti nu. O si n fon ike Re ka. Oun si ni Alaabo, Eleyin
وَمِنْ آيَاتِهِ خَلْقُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَثَّ فِيهِمَا مِنْ دَابَّةٍ ۚ وَهُوَ عَلَىٰ جَمْعِهِمْ إِذَا يَشَاءُ قَدِيرٌ
Ati pe ninu ami Re ni iseda awon sanmo, ile ati nnkan ti O fonka saaarin mejeeji ninu awon nnkan abemi. Oun si ni Alagbara lori ikojo won nigba ti O ba fe

Choose other languages: