Quran Apps in many lanuages:

Surah Ash-Shura Ayahs #14 Translated in Yoruba

وَمَا اخْتَلَفْتُمْ فِيهِ مِنْ شَيْءٍ فَحُكْمُهُ إِلَى اللَّهِ ۚ ذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبِّي عَلَيْهِ تَوَكَّلْتُ وَإِلَيْهِ أُنِيبُ
Ohunkohun ti e ba yapa enu nipa re, idajo re di odo Allahu. Iyen ni Allahu, Oluwa mi. Oun ni mo gbarale. Odo Re si ni mo maa seri pada si (ni ti ironupiwada). oro Allahu ati idajo Re. Pelu agboye yii ayah yii je okan ninu awon ayah t’o n pa wa lase lati fi al-Ƙur’an ati sunnah Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) yanju awon oro iyapa-enu
فَاطِرُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ جَعَلَ لَكُمْ مِنْ أَنْفُسِكُمْ أَزْوَاجًا وَمِنَ الْأَنْعَامِ أَزْوَاجًا ۖ يَذْرَؤُكُمْ فِيهِ ۚ لَيْسَ كَمِثْلِهِ شَيْءٌ ۖ وَهُوَ السَّمِيعُ الْبَصِيرُ
(Oun ni) Olupileda awon sanmo ati ile. O seda awon obinrin fun yin lati ara yin. O tun seda awon abo eran-osin lati ara awon ako eran-osin. O n mu yin po si i (nipa iseda yin ni ako-abo). Ko si kini kan bi iru Re. Oun si ni Olugbo, Oluriran
لَهُ مَقَالِيدُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَنْ يَشَاءُ وَيَقْدِرُ ۚ إِنَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ
TiRe ni awon kokoro apoti-oro awon sanmo ati ile. O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re (fun elomiiran). Dajudaju Oun ni Onimo nipa gbogbo nnkan
شَرَعَ لَكُمْ مِنَ الدِّينِ مَا وَصَّىٰ بِهِ نُوحًا وَالَّذِي أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ وَمَا وَصَّيْنَا بِهِ إِبْرَاهِيمَ وَمُوسَىٰ وَعِيسَىٰ ۖ أَنْ أَقِيمُوا الدِّينَ وَلَا تَتَفَرَّقُوا فِيهِ ۚ كَبُرَ عَلَى الْمُشْرِكِينَ مَا تَدْعُوهُمْ إِلَيْهِ ۚ اللَّهُ يَجْتَبِي إِلَيْهِ مَنْ يَشَاءُ وَيَهْدِي إِلَيْهِ مَنْ يُنِيبُ
(Allahu) se ni ofin fun yin ninu esin (’Islam) ohun ti O pa ni ase fun (Anabi) Nuh ati eyi ti O fi ranse si o, ati ohun ti A pa lase fun (Anabi) ’Ibrohim, (Anabi) Musa ati (Anabi) ‘Isa pe ki e gbe esin naa duro. Ki e si ma se pin si ijo otooto ninu re. Wahala l’o je fun awon osebo nipa nnkan ti o n pe won si (nibi mimu Allahu ni okan soso). Allahu l’O n sesa eni ti O ba fe sinu esin Re (ti o n pe won si). O si n fi ona mo eni ti o ba n seri pada si odo Re (nipase ironupiwada)
وَمَا تَفَرَّقُوا إِلَّا مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَهُمُ الْعِلْمُ بَغْيًا بَيْنَهُمْ ۚ وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِنْ رَبِّكَ إِلَىٰ أَجَلٍ مُسَمًّى لَقُضِيَ بَيْنَهُمْ ۚ وَإِنَّ الَّذِينَ أُورِثُوا الْكِتَابَ مِنْ بَعْدِهِمْ لَفِي شَكٍّ مِنْهُ مُرِيبٍ
(Awon osebo) ko si pin si ijo otooto afi leyin ti imo (’Islam) de ba won. (Won se bee) nipase ote aarin won (si awon Anabi). Ti ko ba je pe oro kan ti siwaju lodo Oluwa re (pe Oun yoo lo won lara) titi di gbedeke akoko kan ni, Won iba ti dajo laaarin won. Dajudaju awon ti A jogun Tira fun leyin won si tun wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa ’Islam

Choose other languages: