Surah Ash-Shura Ayahs #16 Translated in Yoruba
لَهُ مَقَالِيدُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَنْ يَشَاءُ وَيَقْدِرُ ۚ إِنَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ
TiRe ni awon kokoro apoti-oro awon sanmo ati ile. O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re (fun elomiiran). Dajudaju Oun ni Onimo nipa gbogbo nnkan
شَرَعَ لَكُمْ مِنَ الدِّينِ مَا وَصَّىٰ بِهِ نُوحًا وَالَّذِي أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ وَمَا وَصَّيْنَا بِهِ إِبْرَاهِيمَ وَمُوسَىٰ وَعِيسَىٰ ۖ أَنْ أَقِيمُوا الدِّينَ وَلَا تَتَفَرَّقُوا فِيهِ ۚ كَبُرَ عَلَى الْمُشْرِكِينَ مَا تَدْعُوهُمْ إِلَيْهِ ۚ اللَّهُ يَجْتَبِي إِلَيْهِ مَنْ يَشَاءُ وَيَهْدِي إِلَيْهِ مَنْ يُنِيبُ
(Allahu) se ni ofin fun yin ninu esin (’Islam) ohun ti O pa ni ase fun (Anabi) Nuh ati eyi ti O fi ranse si o, ati ohun ti A pa lase fun (Anabi) ’Ibrohim, (Anabi) Musa ati (Anabi) ‘Isa pe ki e gbe esin naa duro. Ki e si ma se pin si ijo otooto ninu re. Wahala l’o je fun awon osebo nipa nnkan ti o n pe won si (nibi mimu Allahu ni okan soso). Allahu l’O n sesa eni ti O ba fe sinu esin Re (ti o n pe won si). O si n fi ona mo eni ti o ba n seri pada si odo Re (nipase ironupiwada)
وَمَا تَفَرَّقُوا إِلَّا مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَهُمُ الْعِلْمُ بَغْيًا بَيْنَهُمْ ۚ وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِنْ رَبِّكَ إِلَىٰ أَجَلٍ مُسَمًّى لَقُضِيَ بَيْنَهُمْ ۚ وَإِنَّ الَّذِينَ أُورِثُوا الْكِتَابَ مِنْ بَعْدِهِمْ لَفِي شَكٍّ مِنْهُ مُرِيبٍ
(Awon osebo) ko si pin si ijo otooto afi leyin ti imo (’Islam) de ba won. (Won se bee) nipase ote aarin won (si awon Anabi). Ti ko ba je pe oro kan ti siwaju lodo Oluwa re (pe Oun yoo lo won lara) titi di gbedeke akoko kan ni, Won iba ti dajo laaarin won. Dajudaju awon ti A jogun Tira fun leyin won si tun wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa ’Islam
فَلِذَٰلِكَ فَادْعُ ۖ وَاسْتَقِمْ كَمَا أُمِرْتَ ۖ وَلَا تَتَّبِعْ أَهْوَاءَهُمْ ۖ وَقُلْ آمَنْتُ بِمَا أَنْزَلَ اللَّهُ مِنْ كِتَابٍ ۖ وَأُمِرْتُ لِأَعْدِلَ بَيْنَكُمُ ۖ اللَّهُ رَبُّنَا وَرَبُّكُمْ ۖ لَنَا أَعْمَالُنَا وَلَكُمْ أَعْمَالُكُمْ ۖ لَا حُجَّةَ بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمُ ۖ اللَّهُ يَجْمَعُ بَيْنَنَا ۖ وَإِلَيْهِ الْمَصِيرُ
Nitori iyen, pepe (sinu ’Islam), ki o si duro sinsin gege bi Won se pa o lase. Ma si se tele ife-inu won. Ki o si so pe: "Mo gbagbo ninu eyikeyii Tira ti Allahu sokale. Won si pa mi lase pe ki ng se deede laaarin yin. Allahu ni Oluwa wa ati Oluwa yin. Tiwa ni awon ise wa. Tiyin si ni awon ise yin. Ko si ija laaarin awa ati eyin. Allahu l’O si maa ko wa jo papo. Odo Re si ni abo eda.”
وَالَّذِينَ يُحَاجُّونَ فِي اللَّهِ مِنْ بَعْدِ مَا اسْتُجِيبَ لَهُ حُجَّتُهُمْ دَاحِضَةٌ عِنْدَ رَبِّهِمْ وَعَلَيْهِمْ غَضَبٌ وَلَهُمْ عَذَابٌ شَدِيدٌ
Awon t’o n ba (Anabi s.a.w.) ja nipa (esin) Allahu leyin igba ti awon eniyan ti gba fun un, eri won maa wo lodo Oluwa won. Ibinu n be lori won. Iya lile si wa fun won
Choose other languages:

Albanian

Amharic

Azerbaijani

Bengali

Bosnian

Bulgarian

Burmese

Chinese

Danish

Dutch

English

Farsi

Filipino

French

Fulah

German

Gujarati

Hausa

Hindi

Indonesian

Italian

Japanese

Jawa

Kazakh

Khmer

Korean

Kurdish

Kyrgyz

Malay

Malayalam

Norwegian

Pashto

Persian

Polish

Portuguese

Punjabi

Russian

Sindhi

Sinhalese

Somali

Spanish

Swahili

Swedish

Tajik

Tamil

Tatar

Telugu

Thai

Turkish

Urdu

Uyghur

Uzbek

Vietnamese

Yoruba
