Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rum Ayahs #25 Translated in Yoruba

وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَ لَكُمْ مِنْ أَنْفُسِكُمْ أَزْوَاجًا لِتَسْكُنُوا إِلَيْهَا وَجَعَلَ بَيْنَكُمْ مَوَدَّةً وَرَحْمَةً ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ
O wa ninu awon ami Re pe, O seda awon aya fun yin lati ara yin nitori ki e le ri ifayabale lodo won. O si fi ife ati ike si aarin yin. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o larojinle
وَمِنْ آيَاتِهِ خَلْقُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَاخْتِلَافُ أَلْسِنَتِكُمْ وَأَلْوَانِكُمْ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِلْعَالِمِينَ
O wa ninu awon ami Re, dida awon sanmo ati ile ati okan-o-jokan awon ede yin ati awon awo ara yin. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun awon onimo
وَمِنْ آيَاتِهِ مَنَامُكُمْ بِاللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَابْتِغَاؤُكُمْ مِنْ فَضْلِهِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَسْمَعُونَ
Ninu awon ami Re ni oorun yin ni ale ati ni osan ati wiwa ti e n wa ninu oore Re (fun ije-imu). Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o n gboro
وَمِنْ آيَاتِهِ يُرِيكُمُ الْبَرْقَ خَوْفًا وَطَمَعًا وَيُنَزِّلُ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَيُحْيِي بِهِ الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ
Ninu awon ami Re tun ni fifi monamona han yin ni ti eru ati ireti. O si n so omi kale lati sanmo. O n fi ta ile ji leyin ti ile ti ku. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o n se laakaye
وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ تَقُومَ السَّمَاءُ وَالْأَرْضُ بِأَمْرِهِ ۚ ثُمَّ إِذَا دَعَاكُمْ دَعْوَةً مِنَ الْأَرْضِ إِذَا أَنْتُمْ تَخْرُجُونَ
Ati pe ninu awon ami Re ni pe sanmo ati ile duro pelu ase Re. Leyin naa, nigba ti O ba pe yin ni ipe kan nigba naa ni eyin yoo maa jade lati inu ile

Choose other languages: