Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rad Ayahs #12 Translated in Yoruba

اللَّهُ يَعْلَمُ مَا تَحْمِلُ كُلُّ أُنْثَىٰ وَمَا تَغِيضُ الْأَرْحَامُ وَمَا تَزْدَادُ ۖ وَكُلُّ شَيْءٍ عِنْدَهُ بِمِقْدَارٍ
Allahu mo ohun ti obinrin kookan ni loyun ati ohun ti ile omo yoo fi din ku (ninu ojo ibimo) ati ohun ti o maa fi lekun. Nnkan kookan l’o si ni odiwon lodo Re
عَالِمُ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ الْكَبِيرُ الْمُتَعَالِ
(Allahu ni) Onimo-ikoko-ati- gbangba. O tobi, O ga
سَوَاءٌ مِنْكُمْ مَنْ أَسَرَّ الْقَوْلَ وَمَنْ جَهَرَ بِهِ وَمَنْ هُوَ مُسْتَخْفٍ بِاللَّيْلِ وَسَارِبٌ بِالنَّهَارِ
Bakan naa ni (lodo Allahu), eni ti o fi oro pamo sinu ninu yin ati eni ti o so o sita pelu eni ti o fi oru boju ati eni ti o n rin kiri ni osan
لَهُ مُعَقِّبَاتٌ مِنْ بَيْنِ يَدَيْهِ وَمِنْ خَلْفِهِ يَحْفَظُونَهُ مِنْ أَمْرِ اللَّهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَا يُغَيِّرُ مَا بِقَوْمٍ حَتَّىٰ يُغَيِّرُوا مَا بِأَنْفُسِهِمْ ۗ وَإِذَا أَرَادَ اللَّهُ بِقَوْمٍ سُوءًا فَلَا مَرَدَّ لَهُ ۚ وَمَا لَهُمْ مِنْ دُونِهِ مِنْ وَالٍ
O n be fun eniyan (kookan) awon molaika ti n gbase funra won; won wa niwaju (eniyan) ati leyin re; won n so (ise owo) re pelu ase Allahu. Dajudaju Allahu ko nii se iyipada nnkan t’o n be lodo ijo kan titi won yoo fi yi nnkan t’o n be ninu emi won pada. Nigba ti Allahu ba gbero aburu kan ro ijo kan, ko si eni t’o le da a pada. Ko si si alaabo kan fun won leyin Re
هُوَ الَّذِي يُرِيكُمُ الْبَرْقَ خَوْفًا وَطَمَعًا وَيُنْشِئُ السَّحَابَ الثِّقَالَ
Oun ni Eni t’o n fi monamona han yin ni iberu ati ni ireti (fun yin). O si n seda esujo t’o su dede

Choose other languages: