Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nur Ayahs #50 Translated in Yoruba

لَقَدْ أَنْزَلْنَا آيَاتٍ مُبَيِّنَاتٍ ۚ وَاللَّهُ يَهْدِي مَنْ يَشَاءُ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُسْتَقِيمٍ
Dajudaju A ti so awon ayah t’o n yanju oro kale. Allahu si n to enikeni ti O ba fe si ona taara (’Islam)
وَيَقُولُونَ آمَنَّا بِاللَّهِ وَبِالرَّسُولِ وَأَطَعْنَا ثُمَّ يَتَوَلَّىٰ فَرِيقٌ مِنْهُمْ مِنْ بَعْدِ ذَٰلِكَ ۚ وَمَا أُولَٰئِكَ بِالْمُؤْمِنِينَ
Won n wi pe: “A gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. A si tele (ase Won).” Leyin naa, igun kan ninu won n peyin da leyin iyen. Awon wonyen ki i se onigbagbo ododo
وَإِذَا دُعُوا إِلَى اللَّهِ وَرَسُولِهِ لِيَحْكُمَ بَيْنَهُمْ إِذَا فَرِيقٌ مِنْهُمْ مُعْرِضُونَ
Ati pe nigba ti won ba pe won si ti Allahu ati ti Ojise Re nitori ki o le sedajo laaarin won, nigba naa ni igun kan ninu won yoo maa gbunri
وَإِنْ يَكُنْ لَهُمُ الْحَقُّ يَأْتُوا إِلَيْهِ مُذْعِنِينَ
Ti o ba si je pe awon ni won ni eto (are) ni, won yoo wa ba o ni tokan-tara
أَفِي قُلُوبِهِمْ مَرَضٌ أَمِ ارْتَابُوا أَمْ يَخَافُونَ أَنْ يَحِيفَ اللَّهُ عَلَيْهِمْ وَرَسُولُهُ ۚ بَلْ أُولَٰئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ
Se arun wa ninu okan won ni tabi won seyemeji? Tabi won n paya pe Allahu ati Ojise Re yoo fi ejo won segbe ni? Rara o. Awon wonyen, awon ni alabosi

Choose other languages: