Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #90 Translated in Yoruba

وَإِذَا حُيِّيتُمْ بِتَحِيَّةٍ فَحَيُّوا بِأَحْسَنَ مِنْهَا أَوْ رُدُّوهَا ۗ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ حَسِيبًا
Nigba ti won ba ki yin ni kiki kan, e ki won (pada) pelu eyi t’o dara ju u lo tabi ki e da a pada (pelu bi won se ki yin). Dajudaju Allahu n je Olusiro lori gbogbo nnkan
اللَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۚ لَيَجْمَعَنَّكُمْ إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ لَا رَيْبَ فِيهِ ۗ وَمَنْ أَصْدَقُ مِنَ اللَّهِ حَدِيثًا
Allahu, ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun. Dajudaju O maa ko yin jo ni Ojo Ajinde, ti ko si iyemeji ninu re. Ta si ni o so ododo ju Allahu lo
فَمَا لَكُمْ فِي الْمُنَافِقِينَ فِئَتَيْنِ وَاللَّهُ أَرْكَسَهُمْ بِمَا كَسَبُوا ۚ أَتُرِيدُونَ أَنْ تَهْدُوا مَنْ أَضَلَّ اللَّهُ ۖ وَمَنْ يُضْلِلِ اللَّهُ فَلَنْ تَجِدَ لَهُ سَبِيلًا
Ki ni o maa mu yin pin si ijo meji nipa awon sobe-selu musulumi! Allahu l’O da won pada seyin nitori ohun ti won se nise. Se e fe fi eni ti Allahu si lona mona ni? Enikeni ti Allahu ba si lona, o o nii ri ona kan fun un
وَدُّوا لَوْ تَكْفُرُونَ كَمَا كَفَرُوا فَتَكُونُونَ سَوَاءً ۖ فَلَا تَتَّخِذُوا مِنْهُمْ أَوْلِيَاءَ حَتَّىٰ يُهَاجِرُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ ۚ فَإِنْ تَوَلَّوْا فَخُذُوهُمْ وَاقْتُلُوهُمْ حَيْثُ وَجَدْتُمُوهُمْ ۖ وَلَا تَتَّخِذُوا مِنْهُمْ وَلِيًّا وَلَا نَصِيرًا
Won fe ki e sai gbagbo gege bi won se sai gbagbo, ki e le jo di egbe kan naa. Nitori naa, e ma se mu ore ayo ninu won titi won fi maa si kuro ninu ilu ebo wa si ilu ’Islam fun aabo esin Allahu. Ti won ba keyin (si sise hijrah naa), e mu won, ki e si pa won nibikibi ti e ba ti ri won. Ki e si ma se mu ore ayo ati oluranlowo kan ninu won
إِلَّا الَّذِينَ يَصِلُونَ إِلَىٰ قَوْمٍ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَهُمْ مِيثَاقٌ أَوْ جَاءُوكُمْ حَصِرَتْ صُدُورُهُمْ أَنْ يُقَاتِلُوكُمْ أَوْ يُقَاتِلُوا قَوْمَهُمْ ۚ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ لَسَلَّطَهُمْ عَلَيْكُمْ فَلَقَاتَلُوكُمْ ۚ فَإِنِ اعْتَزَلُوكُمْ فَلَمْ يُقَاتِلُوكُمْ وَأَلْقَوْا إِلَيْكُمُ السَّلَمَ فَمَا جَعَلَ اللَّهُ لَكُمْ عَلَيْهِمْ سَبِيلًا
Ayafi awon t’o ba dara po mo ijo kan ti adehun n be laaarin eyin ati awon. Tabi won wa ba yin, ti okan won ti pami lati ba yin ja tabi lati ba awon eniyan won ja. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, iba fun won lagbara (akin-okan) lori yin, won iba si ja yin logun. Nitori naa, ti won ba yera fun yin, ti won ko si ja yin logun, ti won si juwo juse sile fun yin, nigba naa Allahu ko fun yin ni ona lori won (lati ja won logun)

Choose other languages: