Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #92 Translated in Yoruba

فَمَا لَكُمْ فِي الْمُنَافِقِينَ فِئَتَيْنِ وَاللَّهُ أَرْكَسَهُمْ بِمَا كَسَبُوا ۚ أَتُرِيدُونَ أَنْ تَهْدُوا مَنْ أَضَلَّ اللَّهُ ۖ وَمَنْ يُضْلِلِ اللَّهُ فَلَنْ تَجِدَ لَهُ سَبِيلًا
Ki ni o maa mu yin pin si ijo meji nipa awon sobe-selu musulumi! Allahu l’O da won pada seyin nitori ohun ti won se nise. Se e fe fi eni ti Allahu si lona mona ni? Enikeni ti Allahu ba si lona, o o nii ri ona kan fun un
وَدُّوا لَوْ تَكْفُرُونَ كَمَا كَفَرُوا فَتَكُونُونَ سَوَاءً ۖ فَلَا تَتَّخِذُوا مِنْهُمْ أَوْلِيَاءَ حَتَّىٰ يُهَاجِرُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ ۚ فَإِنْ تَوَلَّوْا فَخُذُوهُمْ وَاقْتُلُوهُمْ حَيْثُ وَجَدْتُمُوهُمْ ۖ وَلَا تَتَّخِذُوا مِنْهُمْ وَلِيًّا وَلَا نَصِيرًا
Won fe ki e sai gbagbo gege bi won se sai gbagbo, ki e le jo di egbe kan naa. Nitori naa, e ma se mu ore ayo ninu won titi won fi maa si kuro ninu ilu ebo wa si ilu ’Islam fun aabo esin Allahu. Ti won ba keyin (si sise hijrah naa), e mu won, ki e si pa won nibikibi ti e ba ti ri won. Ki e si ma se mu ore ayo ati oluranlowo kan ninu won
إِلَّا الَّذِينَ يَصِلُونَ إِلَىٰ قَوْمٍ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَهُمْ مِيثَاقٌ أَوْ جَاءُوكُمْ حَصِرَتْ صُدُورُهُمْ أَنْ يُقَاتِلُوكُمْ أَوْ يُقَاتِلُوا قَوْمَهُمْ ۚ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ لَسَلَّطَهُمْ عَلَيْكُمْ فَلَقَاتَلُوكُمْ ۚ فَإِنِ اعْتَزَلُوكُمْ فَلَمْ يُقَاتِلُوكُمْ وَأَلْقَوْا إِلَيْكُمُ السَّلَمَ فَمَا جَعَلَ اللَّهُ لَكُمْ عَلَيْهِمْ سَبِيلًا
Ayafi awon t’o ba dara po mo ijo kan ti adehun n be laaarin eyin ati awon. Tabi won wa ba yin, ti okan won ti pami lati ba yin ja tabi lati ba awon eniyan won ja. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, iba fun won lagbara (akin-okan) lori yin, won iba si ja yin logun. Nitori naa, ti won ba yera fun yin, ti won ko si ja yin logun, ti won si juwo juse sile fun yin, nigba naa Allahu ko fun yin ni ona lori won (lati ja won logun)
سَتَجِدُونَ آخَرِينَ يُرِيدُونَ أَنْ يَأْمَنُوكُمْ وَيَأْمَنُوا قَوْمَهُمْ كُلَّ مَا رُدُّوا إِلَى الْفِتْنَةِ أُرْكِسُوا فِيهَا ۚ فَإِنْ لَمْ يَعْتَزِلُوكُمْ وَيُلْقُوا إِلَيْكُمُ السَّلَمَ وَيَكُفُّوا أَيْدِيَهُمْ فَخُذُوهُمْ وَاقْتُلُوهُمْ حَيْثُ ثَقِفْتُمُوهُمْ ۚ وَأُولَٰئِكُمْ جَعَلْنَا لَكُمْ عَلَيْهِمْ سُلْطَانًا مُبِينًا
E maa ri awon elomiiran ti won fe fi yin lokan bale, won si fe fi awon eniyan won lokan bale (pe) nigbakigba ti won ba da won pada sinu ifooro (iborisa) ni won n pada sinu re. Ti won ko ba yera fun yin, ti won ko juwo juse sile fun yin, ti won ko si dawo jija yin logun duro, nigba naa e mu won, ki e si pa won nibikibi ti owo yin ba ti ba won. Awon wonyen ni Allahu si fun yin ni agbara t’o yanju lori won (lati ja won logun)
وَمَا كَانَ لِمُؤْمِنٍ أَنْ يَقْتُلَ مُؤْمِنًا إِلَّا خَطَأً ۚ وَمَنْ قَتَلَ مُؤْمِنًا خَطَأً فَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مُؤْمِنَةٍ وَدِيَةٌ مُسَلَّمَةٌ إِلَىٰ أَهْلِهِ إِلَّا أَنْ يَصَّدَّقُوا ۚ فَإِنْ كَانَ مِنْ قَوْمٍ عَدُوٍّ لَكُمْ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مُؤْمِنَةٍ ۖ وَإِنْ كَانَ مِنْ قَوْمٍ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَهُمْ مِيثَاقٌ فَدِيَةٌ مُسَلَّمَةٌ إِلَىٰ أَهْلِهِ وَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مُؤْمِنَةٍ ۖ فَمَنْ لَمْ يَجِدْ فَصِيَامُ شَهْرَيْنِ مُتَتَابِعَيْنِ تَوْبَةً مِنَ اللَّهِ ۗ وَكَانَ اللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا
Ko letoo fun onigbagbo ododo kan lati pa onigbagbo ododo kan ayafi ti o ba seesi. Eni ti o ba si seesi pa onigbagbo ododo kan, o maa tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. O si maa san owo emi fun awon eniyan oku afi ti won ba fi tore (fun un). Ti o ba si wa ninu awon eniyan kan ti o je ota fun yin, onigbagbo ododo si ni (eni ti won seesi pa), o maa tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. Ti o ba je ijo ti adehun n be laaarin eyin ati awon, o maa san owo emi fun won. O si maa tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. Eni ti ko ba ri eru onigbagbo ododo, o maa gba aawe osu meji ni telentele. (Ona) ironupiwada kan lati odo Allahu (niyi). Allahu n je Onimo, Ologbon

Choose other languages: