Surah An-Nisa Ayahs #95 Translated in Yoruba
سَتَجِدُونَ آخَرِينَ يُرِيدُونَ أَنْ يَأْمَنُوكُمْ وَيَأْمَنُوا قَوْمَهُمْ كُلَّ مَا رُدُّوا إِلَى الْفِتْنَةِ أُرْكِسُوا فِيهَا ۚ فَإِنْ لَمْ يَعْتَزِلُوكُمْ وَيُلْقُوا إِلَيْكُمُ السَّلَمَ وَيَكُفُّوا أَيْدِيَهُمْ فَخُذُوهُمْ وَاقْتُلُوهُمْ حَيْثُ ثَقِفْتُمُوهُمْ ۚ وَأُولَٰئِكُمْ جَعَلْنَا لَكُمْ عَلَيْهِمْ سُلْطَانًا مُبِينًا
E maa ri awon elomiiran ti won fe fi yin lokan bale, won si fe fi awon eniyan won lokan bale (pe) nigbakigba ti won ba da won pada sinu ifooro (iborisa) ni won n pada sinu re. Ti won ko ba yera fun yin, ti won ko juwo juse sile fun yin, ti won ko si dawo jija yin logun duro, nigba naa e mu won, ki e si pa won nibikibi ti owo yin ba ti ba won. Awon wonyen ni Allahu si fun yin ni agbara t’o yanju lori won (lati ja won logun)
وَمَا كَانَ لِمُؤْمِنٍ أَنْ يَقْتُلَ مُؤْمِنًا إِلَّا خَطَأً ۚ وَمَنْ قَتَلَ مُؤْمِنًا خَطَأً فَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مُؤْمِنَةٍ وَدِيَةٌ مُسَلَّمَةٌ إِلَىٰ أَهْلِهِ إِلَّا أَنْ يَصَّدَّقُوا ۚ فَإِنْ كَانَ مِنْ قَوْمٍ عَدُوٍّ لَكُمْ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مُؤْمِنَةٍ ۖ وَإِنْ كَانَ مِنْ قَوْمٍ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَهُمْ مِيثَاقٌ فَدِيَةٌ مُسَلَّمَةٌ إِلَىٰ أَهْلِهِ وَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مُؤْمِنَةٍ ۖ فَمَنْ لَمْ يَجِدْ فَصِيَامُ شَهْرَيْنِ مُتَتَابِعَيْنِ تَوْبَةً مِنَ اللَّهِ ۗ وَكَانَ اللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا
Ko letoo fun onigbagbo ododo kan lati pa onigbagbo ododo kan ayafi ti o ba seesi. Eni ti o ba si seesi pa onigbagbo ododo kan, o maa tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. O si maa san owo emi fun awon eniyan oku afi ti won ba fi tore (fun un). Ti o ba si wa ninu awon eniyan kan ti o je ota fun yin, onigbagbo ododo si ni (eni ti won seesi pa), o maa tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. Ti o ba je ijo ti adehun n be laaarin eyin ati awon, o maa san owo emi fun won. O si maa tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. Eni ti ko ba ri eru onigbagbo ododo, o maa gba aawe osu meji ni telentele. (Ona) ironupiwada kan lati odo Allahu (niyi). Allahu n je Onimo, Ologbon
وَمَنْ يَقْتُلْ مُؤْمِنًا مُتَعَمِّدًا فَجَزَاؤُهُ جَهَنَّمُ خَالِدًا فِيهَا وَغَضِبَ اللَّهُ عَلَيْهِ وَلَعَنَهُ وَأَعَدَّ لَهُ عَذَابًا عَظِيمًا
Enikeni ti o ba moomo pa onigbagbo ododo kan, ina Jahanamo ni esan re. Olusegbere ni ninu re. Allahu yoo binu si i. O maa fi sebi le e. O si ti pese iya t’o tobi sile de e
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا ضَرَبْتُمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ فَتَبَيَّنُوا وَلَا تَقُولُوا لِمَنْ أَلْقَىٰ إِلَيْكُمُ السَّلَامَ لَسْتَ مُؤْمِنًا تَبْتَغُونَ عَرَضَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا فَعِنْدَ اللَّهِ مَغَانِمُ كَثِيرَةٌ ۚ كَذَٰلِكَ كُنْتُمْ مِنْ قَبْلُ فَمَنَّ اللَّهُ عَلَيْكُمْ فَتَبَيَّنُوا ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرًا
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba wa lori irin-ajo ogun esin Allahu, e se pelepele ki e fi mo ododo (nipa awon eniyan). E si ma se so fun eni ti o ba salamo si yin pe ki i se onigbagbo ododo nitori pe eyin n wa dukia isemi aye. Ni odo Allahu kuku ni opolopo oro ogun wa. Bayen ni eyin naa se wa tele, Allahu si se idera (esin) fun yin. Nitori naa, e se pelepele ki e fi mo ododo (nipa awon eniyan naa). Dajudaju Allahu n je Onimo-ikoko ohun ti e n se nise
لَا يَسْتَوِي الْقَاعِدُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ غَيْرُ أُولِي الضَّرَرِ وَالْمُجَاهِدُونَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنْفُسِهِمْ ۚ فَضَّلَ اللَّهُ الْمُجَاهِدِينَ بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنْفُسِهِمْ عَلَى الْقَاعِدِينَ دَرَجَةً ۚ وَكُلًّا وَعَدَ اللَّهُ الْحُسْنَىٰ ۚ وَفَضَّلَ اللَّهُ الْمُجَاهِدِينَ عَلَى الْقَاعِدِينَ أَجْرًا عَظِيمًا
Awon olujokoo sinu ile ninu awon onigbagbo ododo, yato si awon alailera, ati awon olujagun fun esin Allahu pelu dukia won ati emi won, won ko dogba. Allahu fi ipo kan soore ajulo fun awon olujagun fun esin Allahu pelu dukia won ati emi won lori awon olujokoo sinu ile. Olukuluku (won) ni Allahu se adehun ohun rere (Ogba Idera) fun. Allahu gbola fun awon olujagun esin lori awon olujokoo sinu ile pelu esan nla
Choose other languages:

Albanian

Amharic

Azerbaijani

Bengali

Bosnian

Bulgarian

Burmese

Chinese

Danish

Dutch

English

Farsi

Filipino

French

Fulah

German

Gujarati

Hausa

Hindi

Indonesian

Italian

Japanese

Jawa

Kazakh

Khmer

Korean

Kurdish

Kyrgyz

Malay

Malayalam

Norwegian

Pashto

Persian

Polish

Portuguese

Punjabi

Russian

Sindhi

Sinhalese

Somali

Spanish

Swahili

Swedish

Tajik

Tamil

Tatar

Telugu

Thai

Turkish

Urdu

Uyghur

Uzbek

Vietnamese

Yoruba
