Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #77 Translated in Yoruba

وَلَئِنْ أَصَابَكُمْ فَضْلٌ مِنَ اللَّهِ لَيَقُولَنَّ كَأَنْ لَمْ تَكُنْ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَهُ مَوَدَّةٌ يَا لَيْتَنِي كُنْتُ مَعَهُمْ فَأَفُوزَ فَوْزًا عَظِيمًا
Dajudaju ti oore ajulo kan lati odo Allahu ba si te yin lowo, dajudaju o maa soro - bi eni pe ko si ife laaarin eyin ati oun (teletele) - pe: “Yee! Emi iba wa pelu won, emi iba je ere nla.”
فَلْيُقَاتِلْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ الَّذِينَ يَشْرُونَ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا بِالْآخِرَةِ ۚ وَمَنْ يُقَاتِلْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ فَيُقْتَلْ أَوْ يَغْلِبْ فَسَوْفَ نُؤْتِيهِ أَجْرًا عَظِيمًا
Nitori naa, ki awon t’o n fi aye ra orun maa jagun fun esin Allahu. Enikeni ti o ba si jagun nitori esin Allahu, yala won pa a tabi o segun, laipe A maa fun un ni esan nla
وَمَا لَكُمْ لَا تُقَاتِلُونَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَالْمُسْتَضْعَفِينَ مِنَ الرِّجَالِ وَالنِّسَاءِ وَالْوِلْدَانِ الَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا أَخْرِجْنَا مِنْ هَٰذِهِ الْقَرْيَةِ الظَّالِمِ أَهْلُهَا وَاجْعَلْ لَنَا مِنْ لَدُنْكَ وَلِيًّا وَاجْعَلْ لَنَا مِنْ لَدُنْكَ نَصِيرًا
Ki l’o se yin ti e o nii jagun fun esin Allahu, nigba ti awon alailagbara ninu awon okunrin, awon obinrin ati awon omode (si n be lori ile), awon t’o n so pe: “Oluwa wa, mu wa jade kuro ninu ilu yii, ilu awon alabosi. Fun wa ni alaabo kan lati odo Re. Ki O si fun wa ni alaranse kan lati odo Re.”
الَّذِينَ آمَنُوا يُقَاتِلُونَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ۖ وَالَّذِينَ كَفَرُوا يُقَاتِلُونَ فِي سَبِيلِ الطَّاغُوتِ فَقَاتِلُوا أَوْلِيَاءَ الشَّيْطَانِ ۖ إِنَّ كَيْدَ الشَّيْطَانِ كَانَ ضَعِيفًا
Awon t’o gbagbo ni ododo n jagun fun esin Allahu. Awon t’o sai gbagbo si n jagun fun esin orisa. Nitori naa, e ja awon ore Esu logun. Dajudaju ete Esu, o je ohun ti o le
أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ قِيلَ لَهُمْ كُفُّوا أَيْدِيَكُمْ وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَآتُوا الزَّكَاةَ فَلَمَّا كُتِبَ عَلَيْهِمُ الْقِتَالُ إِذَا فَرِيقٌ مِنْهُمْ يَخْشَوْنَ النَّاسَ كَخَشْيَةِ اللَّهِ أَوْ أَشَدَّ خَشْيَةً ۚ وَقَالُوا رَبَّنَا لِمَ كَتَبْتَ عَلَيْنَا الْقِتَالَ لَوْلَا أَخَّرْتَنَا إِلَىٰ أَجَلٍ قَرِيبٍ ۗ قُلْ مَتَاعُ الدُّنْيَا قَلِيلٌ وَالْآخِرَةُ خَيْرٌ لِمَنِ اتَّقَىٰ وَلَا تُظْلَمُونَ فَتِيلًا
Se o o ri awon ti A so fun pe: “E da’wo ogun esin duro, e maa kirun (lo na), ki e si maa yo Zakah.” Sugbon nigba ti A se ogun esin jija ni oran-anyan le won lori, igba naa ni apa kan ninu won n beru awon eniyan bi eni ti n beru Allahu tabi ti iberu re le koko julo. Won si wi pe: "Oluwa wa, nitori ki ni O fi se ogun esin jija ni oran-anyan le wa lori? Kuku lo wa lara di igba die si i." So pe: “Bin-intin ni igbadun aye, orun loore julo fun eni t’o ba beru Allahu. A o si nii sabosi bin-intin si yin.”

Choose other languages: