Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #59 Translated in Yoruba

فَمِنْهُمْ مَنْ آمَنَ بِهِ وَمِنْهُمْ مَنْ صَدَّ عَنْهُ ۚ وَكَفَىٰ بِجَهَنَّمَ سَعِيرًا
Nitori naa, o n be ninu won eni t’o gbagbo ninu re. O si n be ninu won eni t’o seri kuro nibe. Jahanamo si to ni ina t’o n jo
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا بِآيَاتِنَا سَوْفَ نُصْلِيهِمْ نَارًا كُلَّمَا نَضِجَتْ جُلُودُهُمْ بَدَّلْنَاهُمْ جُلُودًا غَيْرَهَا لِيَذُوقُوا الْعَذَابَ ۗ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَزِيزًا حَكِيمًا
Dajudaju awon t’o sai gbagbo ninu awon ayah Wa, laipe A maa mu won wo inu Ina. Igbakigba ti awo ara won ba jona, A oo maa paaro awo ara miiran fun won ki won le maa to iya wo lo. Dajudaju Allahu n je Alagbara, Ologbon
وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ سَنُدْخِلُهُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۖ لَهُمْ فِيهَا أَزْوَاجٌ مُطَهَّرَةٌ ۖ وَنُدْخِلُهُمْ ظِلًّا ظَلِيلًا
Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, A oo mu won wo inu awon Ogba Idera kan, ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Awon iyawo mimo n be fun won ninu re. A si maa fi won si abe iboji t’o maa siji bo won daradara
إِنَّ اللَّهَ يَأْمُرُكُمْ أَنْ تُؤَدُّوا الْأَمَانَاتِ إِلَىٰ أَهْلِهَا وَإِذَا حَكَمْتُمْ بَيْنَ النَّاسِ أَنْ تَحْكُمُوا بِالْعَدْلِ ۚ إِنَّ اللَّهَ نِعِمَّا يَعِظُكُمْ بِهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ كَانَ سَمِيعًا بَصِيرًا
Dajudaju Allahu n pa yin ni ase pe ki e da agbafipamo pada fun awon olowo won. Ati pe nigba ti e ba n dajo laaarin awon eniyan, e dajo pelu deede. Dajudaju Allahu n fi nnkan t’o dara se waasi fun yin. Dajudaju Allahu n je Olugbo, Oluriran
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَطِيعُوا اللَّهَ وَأَطِيعُوا الرَّسُولَ وَأُولِي الْأَمْرِ مِنْكُمْ ۖ فَإِنْ تَنَازَعْتُمْ فِي شَيْءٍ فَرُدُّوهُ إِلَى اللَّهِ وَالرَّسُولِ إِنْ كُنْتُمْ تُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ ۚ ذَٰلِكَ خَيْرٌ وَأَحْسَنُ تَأْوِيلًا
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e tele (ase) Allahu, e tele (ase) Ojise naa ati awon alase ninu yin. Nitori naa, ti e ba yapa enu si kini kan, e seri re si odo Allahu ati Ojise (sollalahu alayhi wa sallam), ti e ba gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Iyen loore julo, o si dara julo fun ikangun oro

Choose other languages: