Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #28 Translated in Yoruba

وَالْمُحْصَنَاتُ مِنَ النِّسَاءِ إِلَّا مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ ۖ كِتَابَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ ۚ وَأُحِلَّ لَكُمْ مَا وَرَاءَ ذَٰلِكُمْ أَنْ تَبْتَغُوا بِأَمْوَالِكُمْ مُحْصِنِينَ غَيْرَ مُسَافِحِينَ ۚ فَمَا اسْتَمْتَعْتُمْ بِهِ مِنْهُنَّ فَآتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ فَرِيضَةً ۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ فِيمَا تَرَاضَيْتُمْ بِهِ مِنْ بَعْدِ الْفَرِيضَةِ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمًا
(O tun je eewo lati fe) awon abileko ninu awon obinrin ayafi awon erubinrin yin. Ofin Allahu niyi lori yin. Won si se eni t’o n be leyin awon wonyen ni eto fun yin pe ki e wa won fe pelu dukia yin; e fe won ni fife iyawo, lai nii ba won se sina (siwaju yigi siso). Eni ti e ba si fe ni fife iyawo, ti e si ti je igbadun oorun ife lara won fun igba die (amo ti e fe ko won sile), e fun won ni sodaaki won. Oran-anyan ni. Ko si si ese fun yin nipa ohun ti e jo yonu si (lati foju fo laaarin ara yin) leyin sodaaki (t’o je oran-anyan). Dajudaju Allahu n je Onimo, Ologbon
وَمَنْ لَمْ يَسْتَطِعْ مِنْكُمْ طَوْلًا أَنْ يَنْكِحَ الْمُحْصَنَاتِ الْمُؤْمِنَاتِ فَمِنْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ مِنْ فَتَيَاتِكُمُ الْمُؤْمِنَاتِ ۚ وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِإِيمَانِكُمْ ۚ بَعْضُكُمْ مِنْ بَعْضٍ ۚ فَانْكِحُوهُنَّ بِإِذْنِ أَهْلِهِنَّ وَآتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ بِالْمَعْرُوفِ مُحْصَنَاتٍ غَيْرَ مُسَافِحَاتٍ وَلَا مُتَّخِذَاتِ أَخْدَانٍ ۚ فَإِذَا أُحْصِنَّ فَإِنْ أَتَيْنَ بِفَاحِشَةٍ فَعَلَيْهِنَّ نِصْفُ مَا عَلَى الْمُحْصَنَاتِ مِنَ الْعَذَابِ ۚ ذَٰلِكَ لِمَنْ خَشِيَ الْعَنَتَ مِنْكُمْ ۚ وَأَنْ تَصْبِرُوا خَيْرٌ لَكُمْ ۗ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Eni ti ko ba lagbara oro ninu yin lati fe awon olominira onigbagbo ododo lobinrin, ki o fe ninu awon erubinrin yin, onigbagbo ododo lobinrin. Allahu nimo julo nipa igbagbo yin, ara kan naa (si) ni yin. Nitori naa, e fe won pelu iyonda awon olowo won. Ki e si fun won ni sodaaki won ni ona t’o dara, (iyen) awon omoluabi (erubinrin), yato si awon asewo ati odoko. Nigba ti won ba si di abileko, ti won ba (tun) lo se sina, ilaji iya ti n be fun awon olominira ni iya ti n be fun won. (Fife erubinrin), iyen wa fun eni t’o n paya inira (sina) ninu yin. Ati pe ki e se suuru loore julo fun yin. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun
يُرِيدُ اللَّهُ لِيُبَيِّنَ لَكُمْ وَيَهْدِيَكُمْ سُنَنَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ وَيَتُوبَ عَلَيْكُمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Allahu fe salaye (ofin) fun yin, O fe to yin si ona awon t’o siwaju yin, O si fe gba ironupiwada yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon
وَاللَّهُ يُرِيدُ أَنْ يَتُوبَ عَلَيْكُمْ وَيُرِيدُ الَّذِينَ يَتَّبِعُونَ الشَّهَوَاتِ أَنْ تَمِيلُوا مَيْلًا عَظِيمًا
Ati pe Allahu fe gba ironupiwada yin. Awon t’o si n tele ife-adun aye si n fe ki e ye kuro (ninu esin) ni yiye t’o tobi
يُرِيدُ اللَّهُ أَنْ يُخَفِّفَ عَنْكُمْ ۚ وَخُلِقَ الْإِنْسَانُ ضَعِيفًا
Allahu fe se irorun fun yin; A si seda eniyan ni ole

Choose other languages: