Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #22 Translated in Yoruba

وَلَيْسَتِ التَّوْبَةُ لِلَّذِينَ يَعْمَلُونَ السَّيِّئَاتِ حَتَّىٰ إِذَا حَضَرَ أَحَدَهُمُ الْمَوْتُ قَالَ إِنِّي تُبْتُ الْآنَ وَلَا الَّذِينَ يَمُوتُونَ وَهُمْ كُفَّارٌ ۚ أُولَٰئِكَ أَعْتَدْنَا لَهُمْ عَذَابًا أَلِيمًا
Ko si ironupiwada fun awon t’o n se aburu titi iku fi de ba okan ninu won, ki o wa wi pe: “Dajudaju emi ronu piwada nisinsin yii.” (Ko tun si ironupiwada) fun awon t’o ku sipo alaigbagbo. Awon wonyen, A ti pese iya eleta elero sile de won
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا يَحِلُّ لَكُمْ أَنْ تَرِثُوا النِّسَاءَ كَرْهًا ۖ وَلَا تَعْضُلُوهُنَّ لِتَذْهَبُوا بِبَعْضِ مَا آتَيْتُمُوهُنَّ إِلَّا أَنْ يَأْتِينَ بِفَاحِشَةٍ مُبَيِّنَةٍ ۚ وَعَاشِرُوهُنَّ بِالْمَعْرُوفِ ۚ فَإِنْ كَرِهْتُمُوهُنَّ فَعَسَىٰ أَنْ تَكْرَهُوا شَيْئًا وَيَجْعَلَ اللَّهُ فِيهِ خَيْرًا كَثِيرًا
Eyin ti e gbagbo ni ododo, ko letoo fun yin lati je awon obinrin mogun pelu ipa (bii sisu obinrin lopo.) E ma si di won lowo lati ko apa kan nnkan ti e fun won lo ayafi ti won ba huwa ibaje ponnbele. E ba won lopo pelu daadaa. Ti e ba korira won, o le je pe e korira kini kan, ki Allahu si ti fi opolopo oore sinu re
وَإِنْ أَرَدْتُمُ اسْتِبْدَالَ زَوْجٍ مَكَانَ زَوْجٍ وَآتَيْتُمْ إِحْدَاهُنَّ قِنْطَارًا فَلَا تَأْخُذُوا مِنْهُ شَيْئًا ۚ أَتَأْخُذُونَهُ بُهْتَانًا وَإِثْمًا مُبِينًا
Ti e ba si fe fi iyawo kan paaro aye iyawo kan, ti e si ti fun okan ninu won ni opolopo dukia, e o gbodo gba nnkan kan ninu re mo. Se eyin yoo gba a ni ti adapa iro (ti e n pa mo won) ati ese to foju han (ti e n da nipa won)
وَكَيْفَ تَأْخُذُونَهُ وَقَدْ أَفْضَىٰ بَعْضُكُمْ إِلَىٰ بَعْضٍ وَأَخَذْنَ مِنْكُمْ مِيثَاقًا غَلِيظًا
Bawo ni eyin se le gba a pada nigba ti o je pe e ti wole to’ra yin, ti won si ti gba adehun t’o nipon lowo yin
وَلَا تَنْكِحُوا مَا نَكَحَ آبَاؤُكُمْ مِنَ النِّسَاءِ إِلَّا مَا قَدْ سَلَفَ ۚ إِنَّهُ كَانَ فَاحِشَةً وَمَقْتًا وَسَاءَ سَبِيلًا
E ma se fe eni ti awon baba yin ti fe ninu awon obinrin ayafi eyi ti o ti re koja. Dajudaju o je iwa ibaje ati ohun ikorira. O si buru ni ona

Choose other languages: