Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #25 Translated in Yoruba

وَكَيْفَ تَأْخُذُونَهُ وَقَدْ أَفْضَىٰ بَعْضُكُمْ إِلَىٰ بَعْضٍ وَأَخَذْنَ مِنْكُمْ مِيثَاقًا غَلِيظًا
Bawo ni eyin se le gba a pada nigba ti o je pe e ti wole to’ra yin, ti won si ti gba adehun t’o nipon lowo yin
وَلَا تَنْكِحُوا مَا نَكَحَ آبَاؤُكُمْ مِنَ النِّسَاءِ إِلَّا مَا قَدْ سَلَفَ ۚ إِنَّهُ كَانَ فَاحِشَةً وَمَقْتًا وَسَاءَ سَبِيلًا
E ma se fe eni ti awon baba yin ti fe ninu awon obinrin ayafi eyi ti o ti re koja. Dajudaju o je iwa ibaje ati ohun ikorira. O si buru ni ona
حُرِّمَتْ عَلَيْكُمْ أُمَّهَاتُكُمْ وَبَنَاتُكُمْ وَأَخَوَاتُكُمْ وَعَمَّاتُكُمْ وَخَالَاتُكُمْ وَبَنَاتُ الْأَخِ وَبَنَاتُ الْأُخْتِ وَأُمَّهَاتُكُمُ اللَّاتِي أَرْضَعْنَكُمْ وَأَخَوَاتُكُمْ مِنَ الرَّضَاعَةِ وَأُمَّهَاتُ نِسَائِكُمْ وَرَبَائِبُكُمُ اللَّاتِي فِي حُجُورِكُمْ مِنْ نِسَائِكُمُ اللَّاتِي دَخَلْتُمْ بِهِنَّ فَإِنْ لَمْ تَكُونُوا دَخَلْتُمْ بِهِنَّ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ وَحَلَائِلُ أَبْنَائِكُمُ الَّذِينَ مِنْ أَصْلَابِكُمْ وَأَنْ تَجْمَعُوا بَيْنَ الْأُخْتَيْنِ إِلَّا مَا قَدْ سَلَفَ ۗ إِنَّ اللَّهَ كَانَ غَفُورًا رَحِيمًا
A se e ni eewo fun yin (lati fe) awon iya yin ati awon omobinrin yin ati awon arabinrin yin ati awon arabinrin baba yin ati awon arabinrin iya yin ati awon omobinrin arakunrin yin ati awon omobinrin arabinrin yin ati awon iya yin ti o fun yin ni oyan mu ati arabinrin yin nipase oyan ati awon iya iyawo yin ati awon omobinrin iyawo yin ti e gba to, eyi t’o wa ninu ile yin, ti e si ti wole to awon iya won, - ti eyin ko ba si ti i wole to won, ko si ese fun yin (lati fe omobinrin won), - ati awon iyawo omo yin, eyi ti o ti ibadi yin jade. (O tun je eewo) lati fe tegbon taburo papo ayafi eyi ti o ti re koja. Dajudaju Allahu, O n je Alaforijin Asake-orun
وَالْمُحْصَنَاتُ مِنَ النِّسَاءِ إِلَّا مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ ۖ كِتَابَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ ۚ وَأُحِلَّ لَكُمْ مَا وَرَاءَ ذَٰلِكُمْ أَنْ تَبْتَغُوا بِأَمْوَالِكُمْ مُحْصِنِينَ غَيْرَ مُسَافِحِينَ ۚ فَمَا اسْتَمْتَعْتُمْ بِهِ مِنْهُنَّ فَآتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ فَرِيضَةً ۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ فِيمَا تَرَاضَيْتُمْ بِهِ مِنْ بَعْدِ الْفَرِيضَةِ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمًا
(O tun je eewo lati fe) awon abileko ninu awon obinrin ayafi awon erubinrin yin. Ofin Allahu niyi lori yin. Won si se eni t’o n be leyin awon wonyen ni eto fun yin pe ki e wa won fe pelu dukia yin; e fe won ni fife iyawo, lai nii ba won se sina (siwaju yigi siso). Eni ti e ba si fe ni fife iyawo, ti e si ti je igbadun oorun ife lara won fun igba die (amo ti e fe ko won sile), e fun won ni sodaaki won. Oran-anyan ni. Ko si si ese fun yin nipa ohun ti e jo yonu si (lati foju fo laaarin ara yin) leyin sodaaki (t’o je oran-anyan). Dajudaju Allahu n je Onimo, Ologbon
وَمَنْ لَمْ يَسْتَطِعْ مِنْكُمْ طَوْلًا أَنْ يَنْكِحَ الْمُحْصَنَاتِ الْمُؤْمِنَاتِ فَمِنْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ مِنْ فَتَيَاتِكُمُ الْمُؤْمِنَاتِ ۚ وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِإِيمَانِكُمْ ۚ بَعْضُكُمْ مِنْ بَعْضٍ ۚ فَانْكِحُوهُنَّ بِإِذْنِ أَهْلِهِنَّ وَآتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ بِالْمَعْرُوفِ مُحْصَنَاتٍ غَيْرَ مُسَافِحَاتٍ وَلَا مُتَّخِذَاتِ أَخْدَانٍ ۚ فَإِذَا أُحْصِنَّ فَإِنْ أَتَيْنَ بِفَاحِشَةٍ فَعَلَيْهِنَّ نِصْفُ مَا عَلَى الْمُحْصَنَاتِ مِنَ الْعَذَابِ ۚ ذَٰلِكَ لِمَنْ خَشِيَ الْعَنَتَ مِنْكُمْ ۚ وَأَنْ تَصْبِرُوا خَيْرٌ لَكُمْ ۗ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Eni ti ko ba lagbara oro ninu yin lati fe awon olominira onigbagbo ododo lobinrin, ki o fe ninu awon erubinrin yin, onigbagbo ododo lobinrin. Allahu nimo julo nipa igbagbo yin, ara kan naa (si) ni yin. Nitori naa, e fe won pelu iyonda awon olowo won. Ki e si fun won ni sodaaki won ni ona t’o dara, (iyen) awon omoluabi (erubinrin), yato si awon asewo ati odoko. Nigba ti won ba si di abileko, ti won ba (tun) lo se sina, ilaji iya ti n be fun awon olominira ni iya ti n be fun won. (Fife erubinrin), iyen wa fun eni t’o n paya inira (sina) ninu yin. Ati pe ki e se suuru loore julo fun yin. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun

Choose other languages: