Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #156 Translated in Yoruba

وَالَّذِينَ آمَنُوا بِاللَّهِ وَرُسُلِهِ وَلَمْ يُفَرِّقُوا بَيْنَ أَحَدٍ مِنْهُمْ أُولَٰئِكَ سَوْفَ يُؤْتِيهِمْ أُجُورَهُمْ ۗ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَحِيمًا
Awon t’o gbagbo ninu Allahu ati awon Ojise Re, ti won ko si ya eni kan soto ninu won, laipe awon wonyen, (Allahu) maa fun won ni esan won. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun
يَسْأَلُكَ أَهْلُ الْكِتَابِ أَنْ تُنَزِّلَ عَلَيْهِمْ كِتَابًا مِنَ السَّمَاءِ ۚ فَقَدْ سَأَلُوا مُوسَىٰ أَكْبَرَ مِنْ ذَٰلِكَ فَقَالُوا أَرِنَا اللَّهَ جَهْرَةً فَأَخَذَتْهُمُ الصَّاعِقَةُ بِظُلْمِهِمْ ۚ ثُمَّ اتَّخَذُوا الْعِجْلَ مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَتْهُمُ الْبَيِّنَاتُ فَعَفَوْنَا عَنْ ذَٰلِكَ ۚ وَآتَيْنَا مُوسَىٰ سُلْطَانًا مُبِينًا
Awon ahlul-kitab n bi o leere pe ki o so tira kan kale lati inu sanmo. Won kuku bi (Anabi) Musa ni ohun ti o tobi ju iyen lo. Won wi pe: “Fi Allahu han wa ni gbangba.” Nitori naa, ohun igbe lati inu sanmo gba won mu nipase abosi owo won. Leyin naa, won tun so oborogidi omo maalu di nnkan ti won josin fun leyin ti awon eri t’o yanju ti de ba won. A tun samoju kuro nibi iyen. A si fun (Anabi) Musa ni eri ponnbele
وَرَفَعْنَا فَوْقَهُمُ الطُّورَ بِمِيثَاقِهِمْ وَقُلْنَا لَهُمُ ادْخُلُوا الْبَابَ سُجَّدًا وَقُلْنَا لَهُمْ لَا تَعْدُوا فِي السَّبْتِ وَأَخَذْنَا مِنْهُمْ مِيثَاقًا غَلِيظًا
A gbe apata soke ori won nitori majemu won. A si so fun won pe: “E gba enu-ona ilu wole ni oluteriba.” A tun so fun won pe: “E ma se tayo enu-ala ni ojo Sabt.” A si gba adehun t’o nipon lowo won
فَبِمَا نَقْضِهِمْ مِيثَاقَهُمْ وَكُفْرِهِمْ بِآيَاتِ اللَّهِ وَقَتْلِهِمُ الْأَنْبِيَاءَ بِغَيْرِ حَقٍّ وَقَوْلِهِمْ قُلُوبُنَا غُلْفٌ ۚ بَلْ طَبَعَ اللَّهُ عَلَيْهَا بِكُفْرِهِمْ فَلَا يُؤْمِنُونَ إِلَّا قَلِيلًا
Nitori yiye ti won funra won ye adehun won, sisaigbagbo won ninu awon oro Allahu, pipa ti won n pa awon Anabi lai letoo ati wiwi ti won n wi pe: “Okan wa ti di.” – rara, Allahu ti fi edidi di okan won ni nitori aigbagbo won. – Nitori naa, won ko nii gbagbo afi die (ninu won)
وَبِكُفْرِهِمْ وَقَوْلِهِمْ عَلَىٰ مَرْيَمَ بُهْتَانًا عَظِيمًا
Ati nitori aigbagbo won ati oro won lori Moryam ni ti ibanilorukoje t’o tobi (Allahu tun fi edidi di okan won)

Choose other languages: