Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #123 Translated in Yoruba

وَلَأُضِلَّنَّهُمْ وَلَأُمَنِّيَنَّهُمْ وَلَآمُرَنَّهُمْ فَلَيُبَتِّكُنَّ آذَانَ الْأَنْعَامِ وَلَآمُرَنَّهُمْ فَلَيُغَيِّرُنَّ خَلْقَ اللَّهِ ۚ وَمَنْ يَتَّخِذِ الشَّيْطَانَ وَلِيًّا مِنْ دُونِ اللَّهِ فَقَدْ خَسِرَ خُسْرَانًا مُبِينًا
Dajudaju mo maa si won lona. Mo maa fi erokero sinu okan won. Mo maa pa won lase, won yo si maa ge eti eran-osin (lati ya a soto fun orisa). Mo maa pa won lase, won yo si maa yi eda Allahu pada." Enikeni ti o ba mu Esu ni ore leyin Allahu, dajudaju o ti sofo ni ofo ponnbele
يَعِدُهُمْ وَيُمَنِّيهِمْ ۖ وَمَا يَعِدُهُمُ الشَّيْطَانُ إِلَّا غُرُورًا
Esu n sadehun fun won, o si n fi ife-iro sinu okan won. Esu ko si sadehun kan fun won bi ko se etan
أُولَٰئِكَ مَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ وَلَا يَجِدُونَ عَنْهَا مَحِيصًا
Awon wonyen, ina Jahanamo ni ibugbe won; won ko si nii ri ibusasi kan
وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ سَنُدْخِلُهُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۖ وَعْدَ اللَّهِ حَقًّا ۚ وَمَنْ أَصْدَقُ مِنَ اللَّهِ قِيلًا
Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si sise rere, A maa mu won wo inu awon Ogba Idera kan, ti odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. (O je) adehun ti Allahu se ni ti ododo. Ta si ni o so ododo ju Allahu lo
لَيْسَ بِأَمَانِيِّكُمْ وَلَا أَمَانِيِّ أَهْلِ الْكِتَابِ ۗ مَنْ يَعْمَلْ سُوءًا يُجْزَ بِهِ وَلَا يَجِدْ لَهُ مِنْ دُونِ اللَّهِ وَلِيًّا وَلَا نَصِيرًا
Ki i se ife-okan yin, bee ni ki i se ife-okan awon ahlu-l-kitab (ni osuwon idajo orun. Amo,) enikeni ti o ba sise aburu kan, A oo san an ni esan re; ko si nii ri alafeyinti tabi alaranse kan leyin Allahu

Choose other languages: