Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Naml Ayahs #40 Translated in Yoruba

فَلَمَّا جَاءَ سُلَيْمَانَ قَالَ أَتُمِدُّونَنِ بِمَالٍ فَمَا آتَانِيَ اللَّهُ خَيْرٌ مِمَّا آتَاكُمْ بَلْ أَنْتُمْ بِهَدِيَّتِكُمْ تَفْرَحُونَ
Nigba ti (iranse) de odo (Anabi) Sulaemon, o so pe: “Se e maa fi owo ran mi lowo ni? Ohun ti Allahu fun mi loore julo si ohun ti e fun mi. Sibesibe, eyin tun n yo lori ebun yin
ارْجِعْ إِلَيْهِمْ فَلَنَأْتِيَنَّهُمْ بِجُنُودٍ لَا قِبَلَ لَهُمْ بِهَا وَلَنُخْرِجَنَّهُمْ مِنْهَا أَذِلَّةً وَهُمْ صَاغِرُونَ
Pada si odo won. Dajudaju a n bo wa ba won pelu awon omo ogun ti won ko le koju re. Dajudaju a maa mu won jade kuro ninu (ilu won) ni eni abuku. Won yo si di eni yepere.”
قَالَ يَا أَيُّهَا الْمَلَأُ أَيُّكُمْ يَأْتِينِي بِعَرْشِهَا قَبْلَ أَنْ يَأْتُونِي مُسْلِمِينَ
(Anabi Sulaemon) so pe: “Eyin ijoye, ewo ninu yin l’o maa gbe ite (Bilƙis) wa ba mi, siwaju ki won to wa ba mi (lati di) musulumi.”
قَالَ عِفْرِيتٌ مِنَ الْجِنِّ أَنَا آتِيكَ بِهِ قَبْلَ أَنْ تَقُومَ مِنْ مَقَامِكَ ۖ وَإِنِّي عَلَيْهِ لَقَوِيٌّ أَمِينٌ
‘Ifrit ninu awon alujannu so pe: “Emi yoo gbe wa fun o siwaju ki o to dide kuro ni aye re. Dajudaju emi ni alagbara, olufokantan lori re.”
قَالَ الَّذِي عِنْدَهُ عِلْمٌ مِنَ الْكِتَابِ أَنَا آتِيكَ بِهِ قَبْلَ أَنْ يَرْتَدَّ إِلَيْكَ طَرْفُكَ ۚ فَلَمَّا رَآهُ مُسْتَقِرًّا عِنْدَهُ قَالَ هَٰذَا مِنْ فَضْلِ رَبِّي لِيَبْلُوَنِي أَأَشْكُرُ أَمْ أَكْفُرُ ۖ وَمَنْ شَكَرَ فَإِنَّمَا يَشْكُرُ لِنَفْسِهِ ۖ وَمَنْ كَفَرَ فَإِنَّ رَبِّي غَنِيٌّ كَرِيمٌ
Eni ti imo kan lati inu tira wa ni odo re so pe: “Emi yoo gbe e wa fun o siwaju ki o to seju.” Nigba ti o ri i ti o de si odo re, o so pe: “Eyi wa ninu oore ajulo Oluwa mi, lati fi dan mi wo boya mo maa dupe tabi mo maa sai moore. Enikeni ti o ba dupe (fun Allahu), o dupe fun emi ara re. Enikeni ti o ba si saimoore, dajudaju Oluwa mi ni Oloro, Alapon-onle.”

Choose other languages: