Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Naml Ayahs #42 Translated in Yoruba

قَالَ يَا أَيُّهَا الْمَلَأُ أَيُّكُمْ يَأْتِينِي بِعَرْشِهَا قَبْلَ أَنْ يَأْتُونِي مُسْلِمِينَ
(Anabi Sulaemon) so pe: “Eyin ijoye, ewo ninu yin l’o maa gbe ite (Bilƙis) wa ba mi, siwaju ki won to wa ba mi (lati di) musulumi.”
قَالَ عِفْرِيتٌ مِنَ الْجِنِّ أَنَا آتِيكَ بِهِ قَبْلَ أَنْ تَقُومَ مِنْ مَقَامِكَ ۖ وَإِنِّي عَلَيْهِ لَقَوِيٌّ أَمِينٌ
‘Ifrit ninu awon alujannu so pe: “Emi yoo gbe wa fun o siwaju ki o to dide kuro ni aye re. Dajudaju emi ni alagbara, olufokantan lori re.”
قَالَ الَّذِي عِنْدَهُ عِلْمٌ مِنَ الْكِتَابِ أَنَا آتِيكَ بِهِ قَبْلَ أَنْ يَرْتَدَّ إِلَيْكَ طَرْفُكَ ۚ فَلَمَّا رَآهُ مُسْتَقِرًّا عِنْدَهُ قَالَ هَٰذَا مِنْ فَضْلِ رَبِّي لِيَبْلُوَنِي أَأَشْكُرُ أَمْ أَكْفُرُ ۖ وَمَنْ شَكَرَ فَإِنَّمَا يَشْكُرُ لِنَفْسِهِ ۖ وَمَنْ كَفَرَ فَإِنَّ رَبِّي غَنِيٌّ كَرِيمٌ
Eni ti imo kan lati inu tira wa ni odo re so pe: “Emi yoo gbe e wa fun o siwaju ki o to seju.” Nigba ti o ri i ti o de si odo re, o so pe: “Eyi wa ninu oore ajulo Oluwa mi, lati fi dan mi wo boya mo maa dupe tabi mo maa sai moore. Enikeni ti o ba dupe (fun Allahu), o dupe fun emi ara re. Enikeni ti o ba si saimoore, dajudaju Oluwa mi ni Oloro, Alapon-onle.”
قَالَ نَكِّرُوا لَهَا عَرْشَهَا نَنْظُرْ أَتَهْتَدِي أَمْ تَكُونُ مِنَ الَّذِينَ لَا يَهْتَدُونَ
O so pe: “E se iyipada irisi ite re fun un, ki a wo o boya o maa da a mo tabi o maa wa ninu awon ti ko nii da a mo.”
فَلَمَّا جَاءَتْ قِيلَ أَهَٰكَذَا عَرْشُكِ ۖ قَالَتْ كَأَنَّهُ هُوَ ۚ وَأُوتِينَا الْعِلْمَ مِنْ قَبْلِهَا وَكُنَّا مُسْلِمِينَ
Nigba ti (Bilƙis) de, won so fun un pe: “Se bi ite re se ri niyi?” O wi pe: "O da bi eni pe ohun ni." (Anabi Sulaemon si so pe): “Won ti fun wa ni imo siwaju Bilƙis. A si je musulumi.”

Choose other languages: