Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Qasas Ayahs #41 Translated in Yoruba

وَقَالَ مُوسَىٰ رَبِّي أَعْلَمُ بِمَنْ جَاءَ بِالْهُدَىٰ مِنْ عِنْدِهِ وَمَنْ تَكُونُ لَهُ عَاقِبَةُ الدَّارِ ۖ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الظَّالِمُونَ
(Anabi) Musa si so pe: “Oluwa mi nimo julo nipa eni ti o mu imona wa lati odo Re ati eni ti atubotan ile (ike) maa je tire. Dajudaju awon alabosi ko nii jere.”
وَقَالَ فِرْعَوْنُ يَا أَيُّهَا الْمَلَأُ مَا عَلِمْتُ لَكُمْ مِنْ إِلَٰهٍ غَيْرِي فَأَوْقِدْ لِي يَا هَامَانُ عَلَى الطِّينِ فَاجْعَلْ لِي صَرْحًا لَعَلِّي أَطَّلِعُ إِلَىٰ إِلَٰهِ مُوسَىٰ وَإِنِّي لَأَظُنُّهُ مِنَ الْكَاذِبِينَ
Fir‘aon wi pe: “Eyin ijoye, emi ko mo pe olohun kan tun wa leyin mi! Nitori naa, Hamon, da ina fun mi, ki o fi mo amo, ki o si ko ile giga kan fun mi nitori ki emi le yoju wo Olohun Musa. (Nitori pe) dajudaju mo n ro o si ara awon opuro.”
وَاسْتَكْبَرَ هُوَ وَجُنُودُهُ فِي الْأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَظَنُّوا أَنَّهُمْ إِلَيْنَا لَا يُرْجَعُونَ
Oun ati awon omo ogun re si segberaga lori ile lai letoo. Won si ro pe dajudaju A o nii da won pada si odo Wa
فَأَخَذْنَاهُ وَجُنُودَهُ فَنَبَذْنَاهُمْ فِي الْيَمِّ ۖ فَانْظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الظَّالِمِينَ
Nitori naa, A gba oun ati awon omo ogun re mu; A ju won sinu agbami odo. Wo bi atubotan awon alabosi ti ri
وَجَعَلْنَاهُمْ أَئِمَّةً يَدْعُونَ إِلَى النَّارِ ۖ وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ لَا يُنْصَرُونَ
A se won ni asiwaju t’o n pepe sinu Ina. Ti o ba si di Ojo Ajinde, A o nii ran won lowo

Choose other languages: