Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Mumtahana Ayahs #13 Translated in Yoruba

وَإِنْ فَاتَكُمْ شَيْءٌ مِنْ أَزْوَاجِكُمْ إِلَى الْكُفَّارِ فَعَاقَبْتُمْ فَآتُوا الَّذِينَ ذَهَبَتْ أَزْوَاجُهُمْ مِثْلَ مَا أَنْفَقُوا ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ الَّذِي أَنْتُمْ بِهِ مُؤْمِنُونَ
Ti kini kan lati odo awon iyawo yin ba bo mo yin lowo si odo awon alaigbagbo, ti e si kore ogun, e fun awon ti iyawo won sa lo ni iru odiwon ohun ti won na (ni owo-ori). Ki e si beru Allahu, Eni ti eyin ni igbagbo ododo ninu Re
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ إِذَا جَاءَكَ الْمُؤْمِنَاتُ يُبَايِعْنَكَ عَلَىٰ أَنْ لَا يُشْرِكْنَ بِاللَّهِ شَيْئًا وَلَا يَسْرِقْنَ وَلَا يَزْنِينَ وَلَا يَقْتُلْنَ أَوْلَادَهُنَّ وَلَا يَأْتِينَ بِبُهْتَانٍ يَفْتَرِينَهُ بَيْنَ أَيْدِيهِنَّ وَأَرْجُلِهِنَّ وَلَا يَعْصِينَكَ فِي مَعْرُوفٍ ۙ فَبَايِعْهُنَّ وَاسْتَغْفِرْ لَهُنَّ اللَّهَ ۖ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Iwo Anabi, nigba ti awon onigbagbo ododo lobinrin ba wa ba o, ti won n se adehun fun o pe awon ko nii fi kini kan sebo si Allahu, awon ko nii jale, awon ko nii se sina, awon ko nii pa omo won, awon ko nii mu adapa iro wa, adapa iro ti won n mu wa laaarin owo won ati ese won (iyen ni gbigbe oyun oloyun fun oko won), awon ko si nii yapa re nibi nnkan daadaa, nigba naa ba won se adehun, ki o si ba won toro aforijin lodo Allahu. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَوَلَّوْا قَوْمًا غَضِبَ اللَّهُ عَلَيْهِمْ قَدْ يَئِسُوا مِنَ الْآخِرَةِ كَمَا يَئِسَ الْكُفَّارُ مِنْ أَصْحَابِ الْقُبُورِ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu ijo kan ti Allahu ti binu si ni ore. Dajudaju won ti soreti nu nipa orun, gege bi awon alaigbagbo t’o wa ninu saree (se soreti nu nipa ike)

Choose other languages: