Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Mujadala Ayahs #6 Translated in Yoruba

الَّذِينَ يُظَاهِرُونَ مِنْكُمْ مِنْ نِسَائِهِمْ مَا هُنَّ أُمَّهَاتِهِمْ ۖ إِنْ أُمَّهَاتُهُمْ إِلَّا اللَّائِي وَلَدْنَهُمْ ۚ وَإِنَّهُمْ لَيَقُولُونَ مُنْكَرًا مِنَ الْقَوْلِ وَزُورًا ۚ وَإِنَّ اللَّهَ لَعَفُوٌّ غَفُورٌ
Awon t’o n fi eyin iyawo won we ti iya won ninu yin, awon iyawo ki i se iya won. Ko si eni ti o je iya won bi ko se iya ti o bi won lomo. Dajudaju won n so aburu ninu oro ati oro iro. Dajudaju Allahu ni Alamoojukuro, Alaforijin
وَالَّذِينَ يُظَاهِرُونَ مِنْ نِسَائِهِمْ ثُمَّ يَعُودُونَ لِمَا قَالُوا فَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مِنْ قَبْلِ أَنْ يَتَمَاسَّا ۚ ذَٰلِكُمْ تُوعَظُونَ بِهِ ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ
Awon t’o n fi eyin iyawo won we ti iya won, leyin naa ti won n seri kuro nibi ohun ti won so, won maa tu eru kan sile loko eru siwaju ki awon mejeeji to le sunmo ara won. Iyen ni A n fi se waasi fun yin. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
فَمَنْ لَمْ يَجِدْ فَصِيَامُ شَهْرَيْنِ مُتَتَابِعَيْنِ مِنْ قَبْلِ أَنْ يَتَمَاسَّا ۖ فَمَنْ لَمْ يَسْتَطِعْ فَإِطْعَامُ سِتِّينَ مِسْكِينًا ۚ ذَٰلِكَ لِتُؤْمِنُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ ۚ وَتِلْكَ حُدُودُ اللَّهِ ۗ وَلِلْكَافِرِينَ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Eni ti ko ba ri (eru), o maa gba aawe osu meji ni telentele siwaju ki awon mejeeji t’o le sunmo ara won. Eni ti ko ba ni agbara (aawe), o maa bo ogota talika. Iyen nitori ki e le ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojise Re. Iwonyi si ni awon enu-ala (ofin) ti Allahu gbe kale fun eda. Iya eleta-elero si wa fun awon alaigbagbo
إِنَّ الَّذِينَ يُحَادُّونَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ كُبِتُوا كَمَا كُبِتَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ ۚ وَقَدْ أَنْزَلْنَا آيَاتٍ بَيِّنَاتٍ ۚ وَلِلْكَافِرِينَ عَذَابٌ مُهِينٌ
Dajudaju awon t’o n yapa Allahu ati Ojise Re, A oo yepere won gege bi A se yepere awon t’o siwaju won. A kuku ti so awon ayah t’o yanju kale. Iya ti i yepere eda si wa fun awon alaigbagbo
يَوْمَ يَبْعَثُهُمُ اللَّهُ جَمِيعًا فَيُنَبِّئُهُمْ بِمَا عَمِلُوا ۚ أَحْصَاهُ اللَّهُ وَنَسُوهُ ۚ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ
Ni ojo ti Allahu yoo gbe gbogbo won dide, O si maa fun won ni iro ohun ti won se nise. Allahu se akosile re, awon si gbagbe re. Allahu si ni Arinu-rode gbogbo nnkan

Choose other languages: