Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Mujadala Ayahs #9 Translated in Yoruba

إِنَّ الَّذِينَ يُحَادُّونَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ كُبِتُوا كَمَا كُبِتَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ ۚ وَقَدْ أَنْزَلْنَا آيَاتٍ بَيِّنَاتٍ ۚ وَلِلْكَافِرِينَ عَذَابٌ مُهِينٌ
Dajudaju awon t’o n yapa Allahu ati Ojise Re, A oo yepere won gege bi A se yepere awon t’o siwaju won. A kuku ti so awon ayah t’o yanju kale. Iya ti i yepere eda si wa fun awon alaigbagbo
يَوْمَ يَبْعَثُهُمُ اللَّهُ جَمِيعًا فَيُنَبِّئُهُمْ بِمَا عَمِلُوا ۚ أَحْصَاهُ اللَّهُ وَنَسُوهُ ۚ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ
Ni ojo ti Allahu yoo gbe gbogbo won dide, O si maa fun won ni iro ohun ti won se nise. Allahu se akosile re, awon si gbagbe re. Allahu si ni Arinu-rode gbogbo nnkan
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۖ مَا يَكُونُ مِنْ نَجْوَىٰ ثَلَاثَةٍ إِلَّا هُوَ رَابِعُهُمْ وَلَا خَمْسَةٍ إِلَّا هُوَ سَادِسُهُمْ وَلَا أَدْنَىٰ مِنْ ذَٰلِكَ وَلَا أَكْثَرَ إِلَّا هُوَ مَعَهُمْ أَيْنَ مَا كَانُوا ۖ ثُمَّ يُنَبِّئُهُمْ بِمَا عَمِلُوا يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۚ إِنَّ اللَّهَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ
Se o o ri i pe dajudaju Allahu mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile ni? Ko si oro ikoko kan laaarin eni meta afi ki Allahu se ikerin won ati eni marun-un afi ki O se ikefa won. Won kere si iyen, won tun po (ju iyen) afi ki O wa pelu won ni ibikibi ti won ba wa. Leyin naa, O maa fun won ni iro ohun ti won se nise ni Ojo Ajinde. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan. ayah yii ko tumo si pe Paapaa Bibe Allahu wa lori ile aye tabi pe Paapaa Bibe Allahu wa pelu eni kookan. Ti Allahu ba se ikeji eni kan tabi O se iketa eni meji bi ko se pe wiwa Allahu pelu eda Re ni pe “Allahu n gbo ohun eda” ninu surah al-Waƙi‘ah; 56:85 isunmo ti Allahu sunmo eda ju bi a se sunmo ara wa lo duro fun bi awon molaika olugbemi-eda se maa sunmo eni kookan ni akoko ti emi ba fe jade lara eda. Eyi rinle bee ninu ayah 83 ati 84 ninu surah naa. Nitori naa isunmo ti Allahu n toka si ninu awon ayah wonyen ati iru won miiran ko tumo si isokale Allahu wa si inu isan orun eda
أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ نُهُوا عَنِ النَّجْوَىٰ ثُمَّ يَعُودُونَ لِمَا نُهُوا عَنْهُ وَيَتَنَاجَوْنَ بِالْإِثْمِ وَالْعُدْوَانِ وَمَعْصِيَتِ الرَّسُولِ وَإِذَا جَاءُوكَ حَيَّوْكَ بِمَا لَمْ يُحَيِّكَ بِهِ اللَّهُ وَيَقُولُونَ فِي أَنْفُسِهِمْ لَوْلَا يُعَذِّبُنَا اللَّهُ بِمَا نَقُولُ ۚ حَسْبُهُمْ جَهَنَّمُ يَصْلَوْنَهَا ۖ فَبِئْسَ الْمَصِيرُ
Se o o ri awon ti A ko oro ikoko fun, leyin naa ti won tun pada sibi ohun ti A ko fun won. Won n bara won so oro ikoko lori ese, abosi ati iyapa Ojise. Nigba ti won ba si de odo re, won yoo ki o ni kiki ti Allahu ko fi ki o. Won si n wi sinu emi won pe: "Ki ni ko je ki Allahu je wa niya lori ohun ti a n wi (ni ikoko)!" Ina Jahnamo maa to won. Won maa wo inu re. Ikangun naa si buru
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا تَنَاجَيْتُمْ فَلَا تَتَنَاجَوْا بِالْإِثْمِ وَالْعُدْوَانِ وَمَعْصِيَتِ الرَّسُولِ وَتَنَاجَوْا بِالْبِرِّ وَالتَّقْوَىٰ ۖ وَاتَّقُوا اللَّهَ الَّذِي إِلَيْهِ تُحْشَرُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba n bara yin so oro ikoko, e ma se so oro ikoko lori ese, abosi ati iyapa Ojise. E bara yin so oro ikoko lori ise rere ati iberu Allahu. E beru Allahu, Eni ti won yoo ko yin jo si odo Re

Choose other languages: