Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Mujadala Ayahs #12 Translated in Yoruba

أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ نُهُوا عَنِ النَّجْوَىٰ ثُمَّ يَعُودُونَ لِمَا نُهُوا عَنْهُ وَيَتَنَاجَوْنَ بِالْإِثْمِ وَالْعُدْوَانِ وَمَعْصِيَتِ الرَّسُولِ وَإِذَا جَاءُوكَ حَيَّوْكَ بِمَا لَمْ يُحَيِّكَ بِهِ اللَّهُ وَيَقُولُونَ فِي أَنْفُسِهِمْ لَوْلَا يُعَذِّبُنَا اللَّهُ بِمَا نَقُولُ ۚ حَسْبُهُمْ جَهَنَّمُ يَصْلَوْنَهَا ۖ فَبِئْسَ الْمَصِيرُ
Se o o ri awon ti A ko oro ikoko fun, leyin naa ti won tun pada sibi ohun ti A ko fun won. Won n bara won so oro ikoko lori ese, abosi ati iyapa Ojise. Nigba ti won ba si de odo re, won yoo ki o ni kiki ti Allahu ko fi ki o. Won si n wi sinu emi won pe: "Ki ni ko je ki Allahu je wa niya lori ohun ti a n wi (ni ikoko)!" Ina Jahnamo maa to won. Won maa wo inu re. Ikangun naa si buru
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا تَنَاجَيْتُمْ فَلَا تَتَنَاجَوْا بِالْإِثْمِ وَالْعُدْوَانِ وَمَعْصِيَتِ الرَّسُولِ وَتَنَاجَوْا بِالْبِرِّ وَالتَّقْوَىٰ ۖ وَاتَّقُوا اللَّهَ الَّذِي إِلَيْهِ تُحْشَرُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba n bara yin so oro ikoko, e ma se so oro ikoko lori ese, abosi ati iyapa Ojise. E bara yin so oro ikoko lori ise rere ati iberu Allahu. E beru Allahu, Eni ti won yoo ko yin jo si odo Re
إِنَّمَا النَّجْوَىٰ مِنَ الشَّيْطَانِ لِيَحْزُنَ الَّذِينَ آمَنُوا وَلَيْسَ بِضَارِّهِمْ شَيْئًا إِلَّا بِإِذْنِ اللَّهِ ۚ وَعَلَى اللَّهِ فَلْيَتَوَكَّلِ الْمُؤْمِنُونَ
Dajudaju oro ikoko (buruku) n wa lati odo Esu nitori ki o le ko ibanuje ba awon t’o gbagbo ni ododo. Ko si le fi kini kan ko inira ba won afi pelu iyonda Allahu. Allahu si ni ki awon onigbagbo ododo gbarale
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا قِيلَ لَكُمْ تَفَسَّحُوا فِي الْمَجَالِسِ فَافْسَحُوا يَفْسَحِ اللَّهُ لَكُمْ ۖ وَإِذَا قِيلَ انْشُزُوا فَانْشُزُوا يَرْفَعِ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا مِنْكُمْ وَالَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ دَرَجَاتٍ ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti won ba so fun yin pe ki e gbara yin laye ninu awon ibujokoo, e gbara yin laye. Allahu yoo f’aye gba yin. Nigba ti won ba so pe: "E dide (sibi ise rere)." E dide (si i). Allahu yoo sagbega awon ipo fun awon t’o gbagbo ni ododo ati awon ti A fun ni imo ninu yin. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا نَاجَيْتُمُ الرَّسُولَ فَقَدِّمُوا بَيْنَ يَدَيْ نَجْوَاكُمْ صَدَقَةً ۚ ذَٰلِكَ خَيْرٌ لَكُمْ وَأَطْهَرُ ۚ فَإِنْ لَمْ تَجِدُوا فَإِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba ba Ojise soro ateso, e fi ore tita siwaju oro ateso yin. Iyen loore julo fun yin. O si fo yin mo julo. Ti e o ba si ri (ore), dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

Choose other languages: