Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #82 Translated in Yoruba

لُعِنَ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ بَنِي إِسْرَائِيلَ عَلَىٰ لِسَانِ دَاوُودَ وَعِيسَى ابْنِ مَرْيَمَ ۚ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَوْا وَكَانُوا يَعْتَدُونَ
A sebi le awon t’o sai gbagbo ninu awon omo ’Isro’il lori ahon (Anabi) Dawud ati ‘Isa omo Moryam. Iyen nitori pe, won yapa (ase Allahu), won si n tayo enu-ala
كَانُوا لَا يَتَنَاهَوْنَ عَنْ مُنْكَرٍ فَعَلُوهُ ۚ لَبِئْسَ مَا كَانُوا يَفْعَلُونَ
Won ki i ko iwa ibaje ti won n se nise laaarin ara won. Ohun ti won n se nise si buru
تَرَىٰ كَثِيرًا مِنْهُمْ يَتَوَلَّوْنَ الَّذِينَ كَفَرُوا ۚ لَبِئْسَ مَا قَدَّمَتْ لَهُمْ أَنْفُسُهُمْ أَنْ سَخِطَ اللَّهُ عَلَيْهِمْ وَفِي الْعَذَابِ هُمْ خَالِدُونَ
O maa ri opolopo ninu won t’o n sore awon t’o sai gbagbo. Ohun ti emi won ti siwaju fun won si buru to bee ge ti Allahu fi binu si won. Olusegbere si ni won ninu Iya
وَلَوْ كَانُوا يُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالنَّبِيِّ وَمَا أُنْزِلَ إِلَيْهِ مَا اتَّخَذُوهُمْ أَوْلِيَاءَ وَلَٰكِنَّ كَثِيرًا مِنْهُمْ فَاسِقُونَ
Ti o ba je pe won gbagbo ninu Allahu ati Anabi (sollalahu alayhi wa sallam), ati ohun ti A sokale fun un, won ko nii mu won ni ore ayo, sugbon opolopo ninu won ni obileje
لَتَجِدَنَّ أَشَدَّ النَّاسِ عَدَاوَةً لِلَّذِينَ آمَنُوا الْيَهُودَ وَالَّذِينَ أَشْرَكُوا ۖ وَلَتَجِدَنَّ أَقْرَبَهُمْ مَوَدَّةً لِلَّذِينَ آمَنُوا الَّذِينَ قَالُوا إِنَّا نَصَارَىٰ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّ مِنْهُمْ قِسِّيسِينَ وَرُهْبَانًا وَأَنَّهُمْ لَا يَسْتَكْبِرُونَ
Dajudaju o maa ri i pe awon eniyan ti ota won le julo si awon t’o gbagbo ni ododo ni awon yehudi ati awon osebo. Dajudaju o si maa ri i pe awon eniyan t’o sunmo awon t’o gbagbo ni ododo julo ni ife ni awon t’o wi pe: “Dajudaju nasara ni awa.” Iyen nitori pe awon alufaa ati olufokansin n be laaarin won. Ati pe dajudaju won ko nii segberaga (si ododo)

Choose other languages: