Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #56 Translated in Yoruba

فَتَرَى الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمْ مَرَضٌ يُسَارِعُونَ فِيهِمْ يَقُولُونَ نَخْشَىٰ أَنْ تُصِيبَنَا دَائِرَةٌ ۚ فَعَسَى اللَّهُ أَنْ يَأْتِيَ بِالْفَتْحِ أَوْ أَمْرٍ مِنْ عِنْدِهِ فَيُصْبِحُوا عَلَىٰ مَا أَسَرُّوا فِي أَنْفُسِهِمْ نَادِمِينَ
Nitori naa, o maa ri awon ti aare wa ninu okan won, ti won yoo maa yara lo saaarin won. Won yoo maa wi pe: “A n beru pe ki apadasi igba ma baa kan wa ni.” O sunmo ki Allahu mu isegun tabi ase kan wa lati odo Re. Won yo si di alabaamo lori ohun ti won fi pamo sinu okan won
وَيَقُولُ الَّذِينَ آمَنُوا أَهَٰؤُلَاءِ الَّذِينَ أَقْسَمُوا بِاللَّهِ جَهْدَ أَيْمَانِهِمْ ۙ إِنَّهُمْ لَمَعَكُمْ ۚ حَبِطَتْ أَعْمَالُهُمْ فَأَصْبَحُوا خَاسِرِينَ
Awon t’o gbagbo ni ododo si maa so pe: "Se awon (yehudi) wonyi ko ni awon t’o fi Allahu bura ti ibura won si lagbara gan-an pe dajudaju awon n be pelu eyin (munafiki)?" Ise won ti baje. Nitori naa, won si di eni ofo
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا مَنْ يَرْتَدَّ مِنْكُمْ عَنْ دِينِهِ فَسَوْفَ يَأْتِي اللَّهُ بِقَوْمٍ يُحِبُّهُمْ وَيُحِبُّونَهُ أَذِلَّةٍ عَلَى الْمُؤْمِنِينَ أَعِزَّةٍ عَلَى الْكَافِرِينَ يُجَاهِدُونَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَلَا يَخَافُونَ لَوْمَةَ لَائِمٍ ۚ ذَٰلِكَ فَضْلُ اللَّهِ يُؤْتِيهِ مَنْ يَشَاءُ ۚ وَاللَّهُ وَاسِعٌ عَلِيمٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, enikeni ti o ba peyinda nibi esin re ninu yin, laipe Allahu maa mu awon eniyan kan wa; O maa nifee won, awon naa maa nifee Re. Won yoo ro fun awon onigbagbo ododo. Won yo si le mo awon alaigbagbo. Won yoo maa jagun esin fun Allahu. Won ko si nii beru eebu eleeebu. Iyen ni oore ajulo Allahu. O n fun eni ti O ba fe. Allahu si ni Olugbooro, Onimo
إِنَّمَا وَلِيُّكُمُ اللَّهُ وَرَسُولُهُ وَالَّذِينَ آمَنُوا الَّذِينَ يُقِيمُونَ الصَّلَاةَ وَيُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَهُمْ رَاكِعُونَ
Allahu ati Ojise Re ati awon t’o gbagbo ni ododo nikan ni ore yin, awon t’o n kirun, ti won si n yo Zakah, awon si ni oludawote-orunkun (lori irun)
وَمَنْ يَتَوَلَّ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَالَّذِينَ آمَنُوا فَإِنَّ حِزْبَ اللَّهِ هُمُ الْغَالِبُونَ
Enikeni ti o ba mu Allahu ati Ojise Re ati awon onigbagbo ododo ni ore; dajudaju ijo Allahu, awon ni olubori

Choose other languages: