Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #104 Translated in Yoruba

قُلْ لَا يَسْتَوِي الْخَبِيثُ وَالطَّيِّبُ وَلَوْ أَعْجَبَكَ كَثْرَةُ الْخَبِيثِ ۚ فَاتَّقُوا اللَّهَ يَا أُولِي الْأَلْبَابِ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ
So pe: “Ohun buruku ati ohun daadaa ko dogba, pupo ohun buruku ibaa jo o loju”. Nitori naa, e beru Allahu, eyin onilaakaye, nitori ki e le jere.”
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَسْأَلُوا عَنْ أَشْيَاءَ إِنْ تُبْدَ لَكُمْ تَسُؤْكُمْ وَإِنْ تَسْأَلُوا عَنْهَا حِينَ يُنَزَّلُ الْقُرْآنُ تُبْدَ لَكُمْ عَفَا اللَّهُ عَنْهَا ۗ وَاللَّهُ غَفُورٌ حَلِيمٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se maa beere nipa awon nnkan sa. Ti A ba fi han yin, o maa ko ipalara ba yin. Ti e ba si beere nipa (awon nnkan t’o ye lati beere nipa esin) nigba ti A n so al-Ƙur’an kale lowo, A maa fi han yin. Allahu ti se amojukuro nipa re. Allahu ni Alaforijin, Alafarada
قَدْ سَأَلَهَا قَوْمٌ مِنْ قَبْلِكُمْ ثُمَّ أَصْبَحُوا بِهَا كَافِرِينَ
Ijo kan kuku ti beere re siwaju yin. Leyin naa, won si di alaigbagbo nipase re
مَا جَعَلَ اللَّهُ مِنْ بَحِيرَةٍ وَلَا سَائِبَةٍ وَلَا وَصِيلَةٍ وَلَا حَامٍ ۙ وَلَٰكِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا يَفْتَرُونَ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ ۖ وَأَكْثَرُهُمْ لَا يَعْقِلُونَ
Allahu ko fi eran bahirah, eran sa’ibah, eran wasilah ati eran ham lole. Sugbon awon t’o sai gbagbo n da adapa iro mo Allahu ni. Opolopo won ni ko se laakaye
وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْا إِلَىٰ مَا أَنْزَلَ اللَّهُ وَإِلَى الرَّسُولِ قَالُوا حَسْبُنَا مَا وَجَدْنَا عَلَيْهِ آبَاءَنَا ۚ أَوَلَوْ كَانَ آبَاؤُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ شَيْئًا وَلَا يَهْتَدُونَ
Nigba ti won ba so fun won pe: “E maa bo wa sibi ohun ti Allahu sokale. (E maa bo wa) si odo Ojise naa.” Won a wi pe: “Ohun ti a ba awon baba wa lori re ti to wa.” Se pelu bi o se je pe awon baba won ko nimo kan kan, ti won ko si mona

Choose other languages: