Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Kahf Ayahs #48 Translated in Yoruba

هُنَالِكَ الْوَلَايَةُ لِلَّهِ الْحَقِّ ۚ هُوَ خَيْرٌ ثَوَابًا وَخَيْرٌ عُقْبًا
Nibe yen, ti Allahu, Oba Ododo ni ijoba. O loore julo ni esan, O si loore julo ni ikangun (rere)
وَاضْرِبْ لَهُمْ مَثَلَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا كَمَاءٍ أَنْزَلْنَاهُ مِنَ السَّمَاءِ فَاخْتَلَطَ بِهِ نَبَاتُ الْأَرْضِ فَأَصْبَحَ هَشِيمًا تَذْرُوهُ الرِّيَاحُ ۗ وَكَانَ اللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ مُقْتَدِرًا
Se akawe ile aye fun won; o da bi omi ti A sokale lati sanmo. Leyin naa, o ropo mo irugbin ile. Leyin naa, (irugbin) di gbigbe, ti ategun n fonka. Allahu si n je Alagbara lori gbogbo nnkan
الْمَالُ وَالْبَنُونَ زِينَةُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَالْبَاقِيَاتُ الصَّالِحَاتُ خَيْرٌ عِنْدَ رَبِّكَ ثَوَابًا وَخَيْرٌ أَمَلًا
Oso isemi aye ni dukia ati awon omo. Awon ise rere t’o maa wa titi laelae loore julo ni esan lodo Oluwa re, o si loore julo ni ireti
وَيَوْمَ نُسَيِّرُ الْجِبَالَ وَتَرَى الْأَرْضَ بَارِزَةً وَحَشَرْنَاهُمْ فَلَمْ نُغَادِرْ مِنْهُمْ أَحَدًا
(Ranti) ojo ti A maa mu awon apata rin lo. O si maa ri ile ni petele. A maa ko won jo. A o si nii fi eni kan sile ninu won
وَعُرِضُوا عَلَىٰ رَبِّكَ صَفًّا لَقَدْ جِئْتُمُونَا كَمَا خَلَقْنَاكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ ۚ بَلْ زَعَمْتُمْ أَلَّنْ نَجْعَلَ لَكُمْ مَوْعِدًا
Won yo si ko won wa siwaju Oluwa re ni owoowo. Dajudaju e ti wa ba Wa (bayii) gege bi A se da yin nigba akoko. Amo e so lai ni eri lowo pe A o nii mu ojo adehun se fun yin

Choose other languages: