Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Kahf Ayahs #50 Translated in Yoruba

الْمَالُ وَالْبَنُونَ زِينَةُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَالْبَاقِيَاتُ الصَّالِحَاتُ خَيْرٌ عِنْدَ رَبِّكَ ثَوَابًا وَخَيْرٌ أَمَلًا
Oso isemi aye ni dukia ati awon omo. Awon ise rere t’o maa wa titi laelae loore julo ni esan lodo Oluwa re, o si loore julo ni ireti
وَيَوْمَ نُسَيِّرُ الْجِبَالَ وَتَرَى الْأَرْضَ بَارِزَةً وَحَشَرْنَاهُمْ فَلَمْ نُغَادِرْ مِنْهُمْ أَحَدًا
(Ranti) ojo ti A maa mu awon apata rin lo. O si maa ri ile ni petele. A maa ko won jo. A o si nii fi eni kan sile ninu won
وَعُرِضُوا عَلَىٰ رَبِّكَ صَفًّا لَقَدْ جِئْتُمُونَا كَمَا خَلَقْنَاكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ ۚ بَلْ زَعَمْتُمْ أَلَّنْ نَجْعَلَ لَكُمْ مَوْعِدًا
Won yo si ko won wa siwaju Oluwa re ni owoowo. Dajudaju e ti wa ba Wa (bayii) gege bi A se da yin nigba akoko. Amo e so lai ni eri lowo pe A o nii mu ojo adehun se fun yin
وَوُضِعَ الْكِتَابُ فَتَرَى الْمُجْرِمِينَ مُشْفِقِينَ مِمَّا فِيهِ وَيَقُولُونَ يَا وَيْلَتَنَا مَالِ هَٰذَا الْكِتَابِ لَا يُغَادِرُ صَغِيرَةً وَلَا كَبِيرَةً إِلَّا أَحْصَاهَا ۚ وَوَجَدُوا مَا عَمِلُوا حَاضِرًا ۗ وَلَا يَظْلِمُ رَبُّكَ أَحَدًا
A maa gbe iwe ise eda kale (fun won). Nigba naa, o maa ri awon elese ti won yoo maa beru nipa ohun ti n be ninu iwe ise won. Won yoo wi pe: “Egbe wa! Iru iwe wo ni eyi na; ko fi ohun kekere ati nla kan sile lai ko o sile?” Won si ba ohun ti won se nise nibe. Oluwa re ko si nii sabosi si eni kan
وَإِذْ قُلْنَا لِلْمَلَائِكَةِ اسْجُدُوا لِآدَمَ فَسَجَدُوا إِلَّا إِبْلِيسَ كَانَ مِنَ الْجِنِّ فَفَسَقَ عَنْ أَمْرِ رَبِّهِ ۗ أَفَتَتَّخِذُونَهُ وَذُرِّيَّتَهُ أَوْلِيَاءَ مِنْ دُونِي وَهُمْ لَكُمْ عَدُوٌّ ۚ بِئْسَ لِلظَّالِمِينَ بَدَلًا
(Ranti) nigba ti A so fun awon molaika pe: “E fori kanle ki (Anabi) Adam.” Won si fori kanle ki i afi ’Iblis, (ti) o je okan ninu awon alujannu. O si safojudi si ase Oluwa re. Nitori naa, se e maa mu oun ati awon aromodomo re ni alafeyinti leyin Mi ni, ota yin si ni won. Pasipaaro t’o buru ni fun awon alabosi

Choose other languages: