Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Isra Ayahs #57 Translated in Yoruba

وَقُلْ لِعِبَادِي يَقُولُوا الَّتِي هِيَ أَحْسَنُ ۚ إِنَّ الشَّيْطَانَ يَنْزَغُ بَيْنَهُمْ ۚ إِنَّ الشَّيْطَانَ كَانَ لِلْإِنْسَانِ عَدُوًّا مُبِينًا
So fun awon erusin Mi pe ki won so oro eyi t’o dara julo. Dajudaju Esu yoo maa da yanpon-yanrin sile laaarin won. Dajudaju Esu je ota ponnbele fun eniyan
رَبُّكُمْ أَعْلَمُ بِكُمْ ۖ إِنْ يَشَأْ يَرْحَمْكُمْ أَوْ إِنْ يَشَأْ يُعَذِّبْكُمْ ۚ وَمَا أَرْسَلْنَاكَ عَلَيْهِمْ وَكِيلًا
Oluwa yin nimo julo nipa yin. Ti O ba fe, O maa ke yin. Tabi ti O ba si fe, O maa je yin niya. A ko ran o pe ki o je oluso lori won
وَرَبُّكَ أَعْلَمُ بِمَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۗ وَلَقَدْ فَضَّلْنَا بَعْضَ النَّبِيِّينَ عَلَىٰ بَعْضٍ ۖ وَآتَيْنَا دَاوُودَ زَبُورًا
Oluwa re nimo julo nipa awon t’o n be ninu awon sanmo ati ile. Dajudaju A ti se oore ajulo fun apa kan awon Anabi lori apa kan. A si fun (Anabi) Dawud ni Zabur
قُلِ ادْعُوا الَّذِينَ زَعَمْتُمْ مِنْ دُونِهِ فَلَا يَمْلِكُونَ كَشْفَ الضُّرِّ عَنْكُمْ وَلَا تَحْوِيلًا
So pe: "E pe awon ti e so nipa won lai ni eri lowo pe won je olohun leyin Re, (e maa ri i pe) won ko ni ikapa lati gbe inira kuro tabi lati se iyipada kan fun yin
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ يَدْعُونَ يَبْتَغُونَ إِلَىٰ رَبِّهِمُ الْوَسِيلَةَ أَيُّهُمْ أَقْرَبُ وَيَرْجُونَ رَحْمَتَهُ وَيَخَافُونَ عَذَابَهُ ۚ إِنَّ عَذَابَ رَبِّكَ كَانَ مَحْذُورًا
Awon wonyen ti won n pe (leyin Re) n wa ategun sodo Oluwa won ni! - Ewo ninu won l’o sunmo (Allahu) julo (bayii)? – Awon naa n reti ike Allahu, won si n paya iya Re. Dajudaju iya Oluwa re je ohun ti won gbodo sora fun

Choose other languages: