Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Isra Ayahs #21 Translated in Yoruba

وَكَمْ أَهْلَكْنَا مِنَ الْقُرُونِ مِنْ بَعْدِ نُوحٍ ۗ وَكَفَىٰ بِرَبِّكَ بِذُنُوبِ عِبَادِهِ خَبِيرًا بَصِيرًا
Meloo meloo ninu awon iran ti A ti parun leyin (Anabi) Nuh! Oluwa re to ni Alamotan, Oluriran nipa awon ese erusin Re
مَنْ كَانَ يُرِيدُ الْعَاجِلَةَ عَجَّلْنَا لَهُ فِيهَا مَا نَشَاءُ لِمَنْ نُرِيدُ ثُمَّ جَعَلْنَا لَهُ جَهَنَّمَ يَصْلَاهَا مَذْمُومًا مَدْحُورًا
Eni ti o ba n gbero (oore) aye yii (nikan), A maa taari ohun ti A ba fe si i ninu re ni kiakia fun eni ti A ba fe. Leyin naa, A maa se ina Jahanamo fun un; o maa wo inu re ni eni yepere, eni eko
وَمَنْ أَرَادَ الْآخِرَةَ وَسَعَىٰ لَهَا سَعْيَهَا وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَأُولَٰئِكَ كَانَ سَعْيُهُمْ مَشْكُورًا
Eni ti o ba si gbero (oore) orun, ti o si se ise re, o si je onigbagbo ododo, awon wonyen, ise won maa je atewogba (pelu esan rere)
كُلًّا نُمِدُّ هَٰؤُلَاءِ وَهَٰؤُلَاءِ مِنْ عَطَاءِ رَبِّكَ ۚ وَمَا كَانَ عَطَاءُ رَبِّكَ مَحْظُورًا
Awon wonyi (t’o n gbero oore aye) ati awon wonyi (t’o n gbero oore orun), gbogbo won ni A n se oore aye fun lati inu ore Oluwa re. Won ko nii di ore Oluwa re lowo (fun ikini keji nile aye)
انْظُرْ كَيْفَ فَضَّلْنَا بَعْضَهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ ۚ وَلَلْآخِرَةُ أَكْبَرُ دَرَجَاتٍ وَأَكْبَرُ تَفْضِيلًا
Wo bi A se fun apa kan won loore ajulo lori apa kan (nile aye). Dajudaju torun tun tobi julo ni ipo, o si tobi julo loore ajulo

Choose other languages: