Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Isra Ayahs #20 Translated in Yoruba

وَإِذَا أَرَدْنَا أَنْ نُهْلِكَ قَرْيَةً أَمَرْنَا مُتْرَفِيهَا فَفَسَقُوا فِيهَا فَحَقَّ عَلَيْهَا الْقَوْلُ فَدَمَّرْنَاهَا تَدْمِيرًا
Nigba ti A ba si gbero lati pa ilu kan run, A maa pa awon onigbedemuke ilu naa lase (rere). Amo won maa sebaje sinu ilu. Oro naa yo si ko le won lori. A o si pa won re patapata
وَكَمْ أَهْلَكْنَا مِنَ الْقُرُونِ مِنْ بَعْدِ نُوحٍ ۗ وَكَفَىٰ بِرَبِّكَ بِذُنُوبِ عِبَادِهِ خَبِيرًا بَصِيرًا
Meloo meloo ninu awon iran ti A ti parun leyin (Anabi) Nuh! Oluwa re to ni Alamotan, Oluriran nipa awon ese erusin Re
مَنْ كَانَ يُرِيدُ الْعَاجِلَةَ عَجَّلْنَا لَهُ فِيهَا مَا نَشَاءُ لِمَنْ نُرِيدُ ثُمَّ جَعَلْنَا لَهُ جَهَنَّمَ يَصْلَاهَا مَذْمُومًا مَدْحُورًا
Eni ti o ba n gbero (oore) aye yii (nikan), A maa taari ohun ti A ba fe si i ninu re ni kiakia fun eni ti A ba fe. Leyin naa, A maa se ina Jahanamo fun un; o maa wo inu re ni eni yepere, eni eko
وَمَنْ أَرَادَ الْآخِرَةَ وَسَعَىٰ لَهَا سَعْيَهَا وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَأُولَٰئِكَ كَانَ سَعْيُهُمْ مَشْكُورًا
Eni ti o ba si gbero (oore) orun, ti o si se ise re, o si je onigbagbo ododo, awon wonyen, ise won maa je atewogba (pelu esan rere)
كُلًّا نُمِدُّ هَٰؤُلَاءِ وَهَٰؤُلَاءِ مِنْ عَطَاءِ رَبِّكَ ۚ وَمَا كَانَ عَطَاءُ رَبِّكَ مَحْظُورًا
Awon wonyi (t’o n gbero oore aye) ati awon wonyi (t’o n gbero oore orun), gbogbo won ni A n se oore aye fun lati inu ore Oluwa re. Won ko nii di ore Oluwa re lowo (fun ikini keji nile aye)

Choose other languages: