Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Isra Ayahs #105 Translated in Yoruba

وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَىٰ تِسْعَ آيَاتٍ بَيِّنَاتٍ ۖ فَاسْأَلْ بَنِي إِسْرَائِيلَ إِذْ جَاءَهُمْ فَقَالَ لَهُ فِرْعَوْنُ إِنِّي لَأَظُنُّكَ يَا مُوسَىٰ مَسْحُورًا
Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni awon ami mesan-an t’o yanju. Bi awon omo ’Isro’il leere wo. Ranti, nigba ti o de odo won, Fir‘aon wi fun un pe: “Dajudaju emi lero pe eleedi ni o, Musa.”
قَالَ لَقَدْ عَلِمْتَ مَا أَنْزَلَ هَٰؤُلَاءِ إِلَّا رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ بَصَائِرَ وَإِنِّي لَأَظُنُّكَ يَا فِرْعَوْنُ مَثْبُورًا
(Anabi Musa) so pe: “O kuku mo pe ko si eni ti o so awon (ami) wonyi kale bi ko se Oluwa awon sanmo ati ile; (o si je) ami t’o yanju. Dajudaju emi naa lero pe eni iparun ni o, Fir‘aon.”
فَأَرَادَ أَنْ يَسْتَفِزَّهُمْ مِنَ الْأَرْضِ فَأَغْرَقْنَاهُ وَمَنْ مَعَهُ جَمِيعًا
Nitori naa, (Fir‘aon) fe ko won laya je lori ile. A si te oun ati awon t’o wa pelu re ri patapata
وَقُلْنَا مِنْ بَعْدِهِ لِبَنِي إِسْرَائِيلَ اسْكُنُوا الْأَرْضَ فَإِذَا جَاءَ وَعْدُ الْآخِرَةِ جِئْنَا بِكُمْ لَفِيفًا
A si so fun awon omo ’Isro’il leyin (iku) re pe: “E maa gbe ori ile naa. Sugbon nigba ti Adehun Ikeyin ba de, A oo mu gbogbo yin wa ni apapo (ni ojo esan)
وَبِالْحَقِّ أَنْزَلْنَاهُ وَبِالْحَقِّ نَزَلَ ۗ وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا مُبَشِّرًا وَنَذِيرًا
A so al-Ƙur’an kale pelu ododo. O si sokale pelu ododo. A ko si ran o nise bi ko se pe (ki o je) oniroo-idunnu ati olukilo

Choose other languages: