Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hajj Ayahs #66 Translated in Yoruba

ذَٰلِكَ بِأَنَّ اللَّهَ هُوَ الْحَقُّ وَأَنَّ مَا يَدْعُونَ مِنْ دُونِهِ هُوَ الْبَاطِلُ وَأَنَّ اللَّهَ هُوَ الْعَلِيُّ الْكَبِيرُ
Iyen nitori pe dajudaju Allahu, Oun ni Ododo. Ati pe dajudaju ohun ti won n pe leyin Re ni iro. Dajudaju Allahu, Oun ni O ga, O tobi
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللَّهَ أَنْزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَتُصْبِحُ الْأَرْضُ مُخْضَرَّةً ۗ إِنَّ اللَّهَ لَطِيفٌ خَبِيرٌ
Se o o ri i pe dajudaju Allahu n so omi kale lati sanmo, ile si maa loraa wa? Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Alamotan
لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۗ وَإِنَّ اللَّهَ لَهُوَ الْغَنِيُّ الْحَمِيدُ
TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Dajudaju Allahu, Oun ma ni Oloro, Olope
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللَّهَ سَخَّرَ لَكُمْ مَا فِي الْأَرْضِ وَالْفُلْكَ تَجْرِي فِي الْبَحْرِ بِأَمْرِهِ وَيُمْسِكُ السَّمَاءَ أَنْ تَقَعَ عَلَى الْأَرْضِ إِلَّا بِإِذْنِهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ بِالنَّاسِ لَرَءُوفٌ رَحِيمٌ
Se o o ri i pe dajudaju Allahu ro ohunkohun t’o wa ninu ile fun yin, ati oko oju-omi t’o n rin ninu agbami odo pelu iyonda Re, O n mu sanmo dani ti ko fi jabo ayafi pelu iyonda Re? Dajudaju Allahu ma ni Alaaanu, Onikee fun awon eniyan
وَهُوَ الَّذِي أَحْيَاكُمْ ثُمَّ يُمِيتُكُمْ ثُمَّ يُحْيِيكُمْ ۗ إِنَّ الْإِنْسَانَ لَكَفُورٌ
Oun si ni Eni t’O se yin ni alaaye, leyin naa O n so yin di oku, leyin naa O maa so yin di alaaye. Dajudaju eniyan ma ni alaimoore

Choose other languages: