Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hajj Ayahs #31 Translated in Yoruba

وَأَذِّنْ فِي النَّاسِ بِالْحَجِّ يَأْتُوكَ رِجَالًا وَعَلَىٰ كُلِّ ضَامِرٍ يَأْتِينَ مِنْ كُلِّ فَجٍّ عَمِيقٍ
Ki o si pe ipe fun awon eniyan fun ise Hajj. Won yoo wa ba o pelu irin ese. Won yo si maa gun awon rakunmi wa lati awon ona jijin
لِيَشْهَدُوا مَنَافِعَ لَهُمْ وَيَذْكُرُوا اسْمَ اللَّهِ فِي أَيَّامٍ مَعْلُومَاتٍ عَلَىٰ مَا رَزَقَهُمْ مِنْ بَهِيمَةِ الْأَنْعَامِ ۖ فَكُلُوا مِنْهَا وَأَطْعِمُوا الْبَائِسَ الْفَقِيرَ
nitori ki won le ri awon anfaani t’o n be fun won ati nitori ki won le seranti oruko Allahu fun awon ojo ti won ti mo lori nnkan ti Allahu pa lese fun won ninu awon eran-osin. Nitori naa, e je ninu re, ki e si fi bo alailera, talika
ثُمَّ لْيَقْضُوا تَفَثَهُمْ وَلْيُوفُوا نُذُورَهُمْ وَلْيَطَّوَّفُوا بِالْبَيْتِ الْعَتِيقِ
Leyin naa, ki won pari ise Hajj won, ki won mu awon eje won se, ki won si yipo Ile Laelae
ذَٰلِكَ وَمَنْ يُعَظِّمْ حُرُمَاتِ اللَّهِ فَهُوَ خَيْرٌ لَهُ عِنْدَ رَبِّهِ ۗ وَأُحِلَّتْ لَكُمُ الْأَنْعَامُ إِلَّا مَا يُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ ۖ فَاجْتَنِبُوا الرِّجْسَ مِنَ الْأَوْثَانِ وَاجْتَنِبُوا قَوْلَ الزُّورِ
Iyen (niyen). Enikeni ti o ba si pataki awon nnkan ti Allahu fi se arisami fun esin ’Islam, o loore julo fun un lodo Oluwa re. Won si se awon eran-osin ni eto fun yin ayafi awon ti won n ka (ni eewo) fun yin. Nitori naa, e jinna si egbin orisa. Ki e si jinna si oro iro
حُنَفَاءَ لِلَّهِ غَيْرَ مُشْرِكِينَ بِهِ ۚ وَمَنْ يُشْرِكْ بِاللَّهِ فَكَأَنَّمَا خَرَّ مِنَ السَّمَاءِ فَتَخْطَفُهُ الطَّيْرُ أَوْ تَهْوِي بِهِ الرِّيحُ فِي مَكَانٍ سَحِيقٍ
(E je) oluduro-deede-ninu-esin fun Allahu, lai nii je osebo si I. Enikeni ti o ba sebo si Allahu, o da bi eni t’o jabo lati oju sanmo, ti eye si gbe e lo tabi (ti) ategun ju u sinu aye t’o jinna

Choose other languages: