Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hadid Ayahs #12 Translated in Yoruba

وَمَا لَكُمْ لَا تُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ ۙ وَالرَّسُولُ يَدْعُوكُمْ لِتُؤْمِنُوا بِرَبِّكُمْ وَقَدْ أَخَذَ مِيثَاقَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ
Ki ni o mu yin ti eyin ko fi nii gba Allahu gbo ni ododo? Ojise si n pe yin nitori ki e le gba Oluwa yin gbo. Allahu si ti gba adehun lowo yin, ti eyin ba je onigbagbo ododo
هُوَ الَّذِي يُنَزِّلُ عَلَىٰ عَبْدِهِ آيَاتٍ بَيِّنَاتٍ لِيُخْرِجَكُمْ مِنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ ۚ وَإِنَّ اللَّهَ بِكُمْ لَرَءُوفٌ رَحِيمٌ
Oun ni Eni t’O n so awon ayah t’o yanju kale fun erusin Re nitori ki o le mu yin kuro ninu awon okunkun wa sinu imole. Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Asake-orun fun yin
وَمَا لَكُمْ أَلَّا تُنْفِقُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَلِلَّهِ مِيرَاثُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ لَا يَسْتَوِي مِنْكُمْ مَنْ أَنْفَقَ مِنْ قَبْلِ الْفَتْحِ وَقَاتَلَ ۚ أُولَٰئِكَ أَعْظَمُ دَرَجَةً مِنَ الَّذِينَ أَنْفَقُوا مِنْ بَعْدُ وَقَاتَلُوا ۚ وَكُلًّا وَعَدَ اللَّهُ الْحُسْنَىٰ ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ
Ki ni o mu yin ti eyin ko fi nii nawo fun esin Allahu? Ti Allahu si ni ogun awon sanmo ati ile. Eni ti o nawo siwaju sisi ilu Mokkah, ti o tun jagun esin, ko dogba laaarin yin (si awon miiran). Awon wonyen ni esan won tobi julo si ti awon t’o nawo leyin igba naa, ti won tun jagun esin. Eni kookan si ni Allahu s’adehun esan rere fun. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
مَنْ ذَا الَّذِي يُقْرِضُ اللَّهَ قَرْضًا حَسَنًا فَيُضَاعِفَهُ لَهُ وَلَهُ أَجْرٌ كَرِيمٌ
Ta ni eni ti o maa ya Allahu ni dukia t’o dara, O si maa sadipele re fun un. Esan alapon-onle si tun wa fun un
يَوْمَ تَرَى الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ يَسْعَىٰ نُورُهُمْ بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَبِأَيْمَانِهِمْ بُشْرَاكُمُ الْيَوْمَ جَنَّاتٌ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ
Ni ojo ti o maa ri awon onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin, ti imole won yoo maa tan niwaju won ati ni owo otun won, (A oo so pe:) "Iro idunnu yin ni oni ni awon Ogba Idera kan ti awon odo n san ni isale re." Olusegbere ni yin ninu re. Iyen si ni erenje nla

Choose other languages: