Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #57 Translated in Yoruba

وَإِذْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ وَالْفُرْقَانَ لَعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ
(E ranti) nigba ti A fun (Anabi) Musa ni Tira ati oro-ipinya nitori ki e le mona
وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ يَا قَوْمِ إِنَّكُمْ ظَلَمْتُمْ أَنْفُسَكُمْ بِاتِّخَاذِكُمُ الْعِجْلَ فَتُوبُوا إِلَىٰ بَارِئِكُمْ فَاقْتُلُوا أَنْفُسَكُمْ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَكُمْ عِنْدَ بَارِئِكُمْ فَتَابَ عَلَيْكُمْ ۚ إِنَّهُ هُوَ التَّوَّابُ الرَّحِيمُ
(E ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe: “Eyin ijo mi, dajudaju eyin sabosi si emi ara yin nipa siso oborogidi omo maalu di orisa. Nitori naa, e ronu piwada si odo Eledaa yin, ki awon ti ko bo maalu pa awon t’o bo o laaarin yin. Iyen l’oore julo fun yin ni odo Eledaa yin. O si maa gba ironupiwada yin. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun
وَإِذْ قُلْتُمْ يَا مُوسَىٰ لَنْ نُؤْمِنَ لَكَ حَتَّىٰ نَرَى اللَّهَ جَهْرَةً فَأَخَذَتْكُمُ الصَّاعِقَةُ وَأَنْتُمْ تَنْظُرُونَ
(E ranti) nigba ti e wi pe: “Musa, a o nii gba o gbo afi ki a ri Allahu ni ojukoroju.” Nitori naa, ohun igbe lati inu sanmo gba yin mu, e si n wo boo
ثُمَّ بَعَثْنَاكُمْ مِنْ بَعْدِ مَوْتِكُمْ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Leyin naa, A ji yin dide leyin iku yin, nitori ki e le dupe (fun Allahu)
وَظَلَّلْنَا عَلَيْكُمُ الْغَمَامَ وَأَنْزَلْنَا عَلَيْكُمُ الْمَنَّ وَالسَّلْوَىٰ ۖ كُلُوا مِنْ طَيِّبَاتِ مَا رَزَقْنَاكُمْ ۖ وَمَا ظَلَمُونَا وَلَٰكِنْ كَانُوا أَنْفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
A tun fi esujo se iboji fun yin. A si tun so (ohun mimu) monnu ati (ohun jije) salwa kale fun yin. E je ninu awon nnkan daadaa ti A pese fun yin. Won ko si sabosi si Wa, sugbon emi ara won ni won n sabosi si

Choose other languages: