Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #228 Translated in Yoruba

وَلَا تَجْعَلُوا اللَّهَ عُرْضَةً لِأَيْمَانِكُمْ أَنْ تَبَرُّوا وَتَتَّقُوا وَتُصْلِحُوا بَيْنَ النَّاسِ ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
E ma se fi Allahu se ikewo fun ibura yin pe e o nii se rere, e o nii sora (nibi iwa ese), e o si nii se atunse laaarin awon eniyan. Allahu ni Olugbo, Onimo
لَا يُؤَاخِذُكُمُ اللَّهُ بِاللَّغْوِ فِي أَيْمَانِكُمْ وَلَٰكِنْ يُؤَاخِذُكُمْ بِمَا كَسَبَتْ قُلُوبُكُمْ ۗ وَاللَّهُ غَفُورٌ حَلِيمٌ
Allahu ko nii fi ibura yin ti ko ti inu yin wa bi yin, sugbon O maa fi ohun ti o ba t’inu okan yin wa bi yin. Allahu ni Alaforijin, Alafarada
لِلَّذِينَ يُؤْلُونَ مِنْ نِسَائِهِمْ تَرَبُّصُ أَرْبَعَةِ أَشْهُرٍ ۖ فَإِنْ فَاءُوا فَإِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Ikoraro fun osu merin wa fun awon t’o bura pe awon ko nii sunmo obinrin won. Ti won ba seri pada (laaarin igba naa), dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun
وَإِنْ عَزَمُوا الطَّلَاقَ فَإِنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Ti won ba si pinnu ikosile, (ki won ko won sile.) Dajudaju Allahu ni Olugbo, Onimo
وَالْمُطَلَّقَاتُ يَتَرَبَّصْنَ بِأَنْفُسِهِنَّ ثَلَاثَةَ قُرُوءٍ ۚ وَلَا يَحِلُّ لَهُنَّ أَنْ يَكْتُمْنَ مَا خَلَقَ اللَّهُ فِي أَرْحَامِهِنَّ إِنْ كُنَّ يُؤْمِنَّ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ ۚ وَبُعُولَتُهُنَّ أَحَقُّ بِرَدِّهِنَّ فِي ذَٰلِكَ إِنْ أَرَادُوا إِصْلَاحًا ۚ وَلَهُنَّ مِثْلُ الَّذِي عَلَيْهِنَّ بِالْمَعْرُوفِ ۚ وَلِلرِّجَالِ عَلَيْهِنَّ دَرَجَةٌ ۗ وَاللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Awon obinrin ti won ko sile maa kora ro fun nnkan osu meta. Ko si letoo fun won lati fi ohun ti Allahu s’eda (re) s’inu apo-omo won pamo, ti won ba je eni to gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Awon oko won ni eto si dida won pada l’aaarin (asiko) yen, ti won ba gbero atunse. Awon iyawo ni eto l’odo oko won gege bi iru eyi ti awon oko won ni l’odo won lona t’o dara. Ipo ajulo tun wa fun awon okunrin lori won. Allahu ni Alagbara, Ologbon

Choose other languages: